Hosea 5:15
“Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.””
Hosea 5:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 15 of 15 in Hosea chapter 5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Hosea 5 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
“Ẹ gbọ́ èyí, ẹ̀yìn àlùfáà! Ẹ fetísílẹ̀ ẹ̀yin ọmọ ẹli! Ẹ gbọ́, ẹ̀yìn ilé ọba! Ìdájọ́ yìí kàn yín. Ẹ ti jẹ́ ẹ̀bìtì ní àwọ̀n ti a nà sílẹ̀ lórí . Àwọn ọlọ̀tẹ̀ ti gbilẹ̀ nínú ìpànìyàn gbogbo wọn ni èmi ó bá wí, mo mọ ohun gbogbo nípa ẹli kò sì pamọ́ fún mi , ní báyìí ó ti ṣe àgbèrè ẹli sì ti díbàjẹ́. “Ìṣe wọn kò gbà wọ́n láààyè láti padà sí ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wọn. Ẹ̀mí àgbèrè wà ni ọkàn wọn, wọn kò sì mọ Olúwa. Ìgbéraga ẹli ń jẹ́rìí lé wọn; àwọn ọmọ ẹli, àti pàápàá kọsẹ̀ nínú ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Juda náà sì kọsẹ̀ pẹ̀lú wọn. Nígbà tí wọ́n bá lọ pẹ̀lú agbo ẹran àti ọ̀wọ́ ẹran wọn láti wá Olúwa, wọn kò ní rí i, ó ti yọ ara rẹ̀ kúrò láàrín wọn. Wọ́n jẹ́ aláìṣòótọ́ sí Olúwa wọ́n sì bí àwọn àjèjì ọmọ. Nísinsin yìí, ọdún oṣù tuntun wọn, ni yóò pa wọn run pẹ̀lú ìpín wọn. “Fọn fèrè ní , kí ẹ sì fun ìpè ní . Ẹ pariwo ogun ní -; máa wárìrì, ìwọ . Efraimu yóò di ahoro ní ọjọ́ ìbáwí láàrín àwọn ẹ̀yà ẹli, Mo sọ ohun tí ó dájú. Àwọn olórí dàbí àwọn tí í máa yí òkúta ààlà kúrò. Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi lé wọn lórí bí ìkún omi. A ni lára, a sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́, nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà. Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí , Mo sì dàbí ìdin ara . “Nígbà ti ri àìsàn rẹ̀, tí sì rí ojú egbò rẹ̀ ni bá tọ ará lọ, ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́. Ṣùgbọ́n kò le è wò ó sàn bẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná. Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí , bí i kìnnìún ńlá sí ilé . Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ; Èmi ó gbé wọn lọ, láìsí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mi títí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀bi wọn yóò sì wá ojú mi nínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”
Every verse in Hosea 5
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.