Isaiah 12:3

“Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà.”

Isaiah 12:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 3 of 6 in Isaiah chapter 12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 12 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ọjọ́ náà ni ìwọ ó wí pé, “Èmi ó yìn ọ́, Olúwa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ò ti bínú sí mi ìbínú rẹ ti yí kúrò níbẹ̀ ìwọ sì ti tù mí nínú. Nítòótọ́ Ọlọ́run ni ìgbàlà mi, èmi yóò gbẹ́kẹ̀lé e èmi kì yóò bẹ̀rù. Olúwa, Olúwa náà ni agbára à mi àti orin ìn mi, òun ti di ìgbàlà mi.” Pẹ̀lú ayọ̀ ni ìwọ yóò máa pọn omi láti inú kànga ìgbàlà. Ní ọjọ́ náà, ìwọ yóò wí pé, “Fi ọpẹ́ fún Olúwa, ké pe orúkọ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mí mọ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun tí ó ti ṣe kí o sì kéde pé a ti gbé orúkọ rẹ̀ ga. Kọ orin sí Olúwa, nítorí ó ti ṣe ohun tí ó lógo, jẹ́ kí èyí di mí mọ̀ fún gbogbo ayé. Kígbe sókè kí o sì kọrin fún ayọ̀, ẹ̀yin ènìyàn , nítorí títóbi ni ẹni mímọ́ kan ṣoṣo ti ẹli láàrín yín.”

Every verse in Isaiah 12

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00