Isaiah 16:14

“Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.””

Isaiah 16:14 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 14 of 14 in Isaiah chapter 16 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 16 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà, láti , kọjá ní aginjù, lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin . Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin ní àwọn ìwọdò . “Fún wa ní ìmọ̀ràn ṣe ìpinnu fún wa. Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru, ní ọ̀sán gangan. Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́, má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han. Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá gbé pẹ̀lú rẹ, jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.” ára yóò wá sí òpin, ìparun yóò dáwọ́ dúró; òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀. Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀, ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀ ẹnìkan láti ilé wá. Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́, yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo. Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga , ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge, gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo. Nítorí náà ni àwọn ará hu, wọ́n jùmọ̀ hu lórí . Sọkún kí o sì banújẹ́ fún àkàrà díndín -. Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ, bákan náà ni àjàrà rí. Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀, èyí tí ó ti fà dé ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù. Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde, ó sì lọ títí ó fi dé Òkun. Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí ṣe sọkún, fún àwọn àjàrà . Ìwọ Heṣboni, ìwọ , mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú! Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́ dúró. Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò nínú ọgbà-igi eléso rẹ; kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí kígbe nínú ọgbà àjàrà: ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí, nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe. Ọkàn mi kérora fún gẹ́gẹ́ bí i dùùrù, àní tọkàntọkàn mi fún ìlú -. Nígbà tí farahàn ní ibi gíga rẹ̀, ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán; nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà òfo ni ó jásí. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa . Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé, “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

Every verse in Isaiah 16

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00