Isaiah 18:6

“A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò.”

Isaiah 18:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 7 in Isaiah chapter 18 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 18 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ègbé ni fún ilẹ̀ tí ó kún fún ariwo ìyẹ́ eṣú, ní àwọn ipadò Kuṣi, tí ó rán àwọn ikọ̀ lórí Òkun lórí omi nínú ọkọ̀-ọpọ́n tí a fi eèsún papirusi ṣe. Ẹ lọ, ẹ̀yin ikọ̀ tí ó yára, sí àwọn ènìyàn gíga tí àwọ̀ ara wọn jọ̀lọ̀, sí àwọn ènìyàn tí a ń bẹ̀rù káàkiri, orílẹ̀-èdè aláfojúdi alájèjì èdè, tí odò pín ilẹ̀ rẹ̀ yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Gbogbo ẹ̀yin ènìyàn ayé, tí ó ń gbé orílẹ̀ ayé, nígbà tí a bá gbé àsíá kan sókè lórí òkè, ẹ ó rí i, nígbà tí a bá fun fèrè kan ẹ ó gbọ́ ọ. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Èmi yóò dákẹ́ jẹ́ẹ́, èmi yóò sì máa wo òréré láti ibùgbé e mi wá, gẹ́gẹ́ bí ooru gbígbóná nínú ìtànṣán oòrùn, gẹ́gẹ́ bí òjò-dídì ní àárín gbùngbùn ìkórè.” Nítorí, kí ìkórè tó bẹ̀rẹ̀, nígbà tí ìrudí bá kún, nígbà tí ìtànná bá di èso àjàrà pípọ́n. Òun yóò sì fi dòjé rẹ́ ẹ̀ka tuntun, yóò sì mu kúrò, yóò sì gé ẹ̀ka lulẹ̀. A ó fi wọ́n sílẹ̀ fún àwọn ẹyẹ òkè ńlá àti fún àwọn ẹranko búburú; àwọn ẹyẹ yóò fi wọ́n ṣe oúnjẹ nínú ẹ̀ẹ̀rùn àti àwọn ẹranko búburú nígbà òjò. Ní àkókò náà ni a ó mú ẹ̀bùn wá fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn gíga tí ẹran-ara wọn jọ̀lọ̀, láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí a bẹ̀rù níbi gbogbo, orílẹ̀-èdè aláfojúdi àti alájèjì èdè, ilẹ̀ ẹni tí omi pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ— a ó mú àwọn ẹ̀bùn náà wá sí òkè , ibi tí orúkọ Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbé wà.

Every verse in Isaiah 18

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00