Isaiah 19:3
“Àwọn ará Ejibiti yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀.”
Isaiah 19:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 25 in Isaiah chapter 19 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Isaiah 19 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan . Kíyèsi i, Olúwa gun àwọsánmọ̀ tí ó yára lẹ́ṣin ó sì ń bọ̀ wá sí . Àwọn ère òrìṣà wárìrì níwájú rẹ̀, ọkàn àwọn ará sì ti domi nínú wọn. “Èmi yóò rú àwọn ará sókè sí ara wọn arákùnrin yóò bá arákùnrin rẹ̀ jà, aládùúgbò yóò dìde sí aládùúgbò rẹ̀, ìlú yóò dìde sí ìlú, ilẹ̀ ọba sí ilẹ̀ ọba. Àwọn ará yóò sọ ìrètí nù, èmi yóò sì sọ èrò wọn gbogbo di òfo; wọn yóò bá àwọn òrìṣà àti ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀, àwọn awoṣẹ́ àti àwọn abókùúsọ̀rọ̀. Èmi yóò fi lé agbára àwọn ìkà amúnisìn lọ́wọ́, ọba aláìláàánú ni yóò jẹ ọba lé wọn lórí,” ni Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. Gbogbo omi inú odò ni yóò gbẹ, gbogbo ilẹ̀ àyíká odò ni yóò gbẹ tí yóò sì sáàpá. Adágún omi yóò sì di rírùn; àwọn odò ilẹ̀ yóò máa dínkù wọn yóò sì gbẹ. Àwọn koríko odò àti ìrẹ̀tẹ̀ yóò gbẹ, àwọn igi ipadò pẹ̀lú, tí ó wà ní orísun odò, gbogbo oko tí a dá sí ipadò yóò gbẹ dànù tí yóò sì fẹ́ dànù tí kò sì ní sí mọ́. Àwọn apẹja yóò sọkún kíkorò, àti gbogbo àwọn tí ó ń ju ìwọ̀ sínú odò; odò náà yóò sì máa rùn. Àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ yóò kọminú àwọn ahunṣọ ọ̀gbọ̀ yóò sọ ìrètí nù. Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ aṣọ yóò rẹ̀wẹ̀sì, gbogbo àwọn íṣẹ́ oṣù ni àìsàn ọkàn yóò ṣe. Àwọn íṣẹ́ Ṣoani ti di aláìgbọ́n, àwọn ọlọ́gbọ́n olùdámọ̀ràn ń mú ìmọ̀ràn àìgbọ́n wá. Báwo ló ṣe lè sọ fún pé, “Mo jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn àwọn ọba àtijọ́.” Níbo ni àwọn ọlọ́gbọ́n ènìyàn rẹ wà báyìí? Jẹ́ kí wọn fihàn ọ́ kí wọn sì sọ ọ́ di mí mọ̀ ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti pinnu lórí . Àwọn ọmọ-aládé Ṣoani ti di aṣiwèrè, a ti tan àwọn ọmọ-aládé jẹ; àwọn òkúta igun ilé tí í ṣe ti ẹ̀yà rẹ ti ṣi lọ́nà. Olúwa ti da ẹ̀mí òòyì sínú wọn; wọ́n mú ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú ohun gbogbo tí ó ń ṣe, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mùtí ti í ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n nínú èébì rẹ̀. Kò sí ohun tí le ṣe— orí tàbí ìrù, ọ̀wá ọ̀pẹ tàbí koríko odò. Ní ọjọ́ náà ni àwọn ará yóò dàbí obìnrin. Wọn yóò gbọ̀n jìnnìjìnnì pẹ̀lú ẹ̀rù nítorí ọwọ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun tí a gbé sókè sí wọn. Ilẹ̀ yóò sì di ẹ̀rù fún ; gbogbo àwọn tí a bá ti dárúkọ létí wọn ni yóò wárìrì, nítorí ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun gbèrò láti ṣe sí wọn. Ní ọjọ́ náà ìlú márùn-ún ní ilẹ̀ yóò sọ èdè àwọn ará , wọn yóò sì búra àtìlẹ́yìn fún Olúwa àwọn ọmọ-ogun. Ọ̀kan nínú wọn ni a ó sì máa pè ní ìlú ìparun. Ní ọjọ́ náà pẹpẹ kan yóò wà fún Olúwa ní àárín gbùngbùn , àti ọ̀wọ́n kan fún Olúwa ní etí bodè rẹ̀. Yóò sì jẹ́ àmì àti ẹ̀rí sí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ilẹ̀ . Nígbà tí wọ́n bá ké pe Olúwa nítorí àwọn aninilára wọn, yóò rán olùgbàlà àti olùgbèjà kan sí wọn tí yóò sì gbà wọ́n sílẹ̀. Báyìí ni Olúwa yóò sọ ara rẹ̀ di mí mọ̀ fún àwọn ará àti ní ọjọ́ náà ni wọn yóò gba Olúwa gbọ́. Wọn yóò sìn ín pẹ̀lú ẹbọ ọrẹ ìyẹ̀fun, wọn yóò jẹ́ ẹ̀jẹ́ fún Olúwa wọn yóò sì mú un ṣẹ. Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-ààrùn kan bá jà; yóò bá wọn jà yóò sì tún wò wọ́n sàn. Wọn yóò yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì gbọ́ ẹ̀bẹ̀ wọn yóò sì wò wọ́n sàn. Ní ọjọ́ náà òpópónà kan yóò wá láti lọ sí . Àwọn ará yóò lọ sí àti àwọn ará lọ sí . Àwọn ará àti ará yóò jọ́sìn papọ̀. Ní ọjọ́ náà ẹli yóò di ẹ̀kẹta pẹ̀lú àti , àní orísun ìbùkún ní ilẹ̀ ayé. Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò bùkún wọn yóò wí pé, “Ìbùkún ni fún ènìyàn mi, Asiria iṣẹ́ ọwọ́ mi, àti ẹli ìní mi.”
Every verse in Isaiah 19
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.