Isaiah 23:13

“Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará Babeli, àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn Asiria ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn.”

Isaiah 23:13 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 13 of 18 in Isaiah chapter 23 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 23 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ọ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan . Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi ṣiṣi! Nítorí a ti pa run láìsí ilé tàbí èbúté. Láti ilẹ̀ ọsi ni ọ̀rọ̀ ti wá sọ́dọ̀ wọn. Dákẹ́ jẹ́ẹ́, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù àti ẹ̀yin íṣòwò ti , ẹ̀yin tí àwọn a wẹ Òkun ti sọ dọlọ́rọ̀. Láti orí àwọn omi ńlá ni irúgbìn ìyẹ̀fun ti ilẹ̀ Ṣihori ti wá; ìkórè ti odò ni owóòná , òun sì ti di ibùjókòó ọjà fún àwọn orílẹ̀-èdè. Kí ojú kí ó tì ọ́, ìwọ àti ìwọ àní ìwọ ilé ààbò ti Òkun, nítorí Òkun ti sọ̀rọ̀. “Èmi kò tí ì wà ní ipò ìrọbí tàbí ìbímọ rí Èmi kò tí ì wo àwọn ọmọkùnrin tàbí kí n tọ́ àwọn ọmọbìnrin dàgbà rí.” Nígbà tí ọ̀rọ̀ bá dé , wọn yóò wà ní ìpayínkeke nípa ìròyìn láti . Kọjá wá sí ṣiṣi; pohùnréré, ẹ̀yin ènìyàn erékùṣù. Ǹjẹ́ èyí náà ni ìlú àríyá yín, ògbólógbòó ìlú náà, èyí tí ẹsẹ̀ rẹ̀ ti sìn ín lọ láti lọ tẹ̀dó sí ilẹ̀ tí ó jìnnà réré. Ta ló gbèrò èyí sí , ìlú aládé, àwọn íṣòwò ẹni tí ó jẹ́ ọmọ-aládé tí àwọn íṣòwò wọ́n jẹ́ ìlúmọ̀míká ní orílẹ̀ ayé? Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti ṣètò rẹ̀, láti tẹrí ìgbéraga àti ògo rẹ ba àti láti rẹ gbogbo àwọn ọlọ́lá ilé ayé sílẹ̀. Tu ilẹ̀ rẹ gẹ́gẹ́ bí i ti ipadò odò , ìwọ ọmọbìnrin ṣiṣi, nítorí ìwọ kò ní èbúté mọ́. Olúwa ti na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí orí Òkun ó sì mú kí àwọn ilẹ̀ ọba wárìrì. Ó ti pa àṣẹ kan tí ó kan pé kí a pa ilé ààbò rẹ̀ run. Ó wí pé, “Kò sí àríyá fún ọ mọ́, ìwọ wúńdíá ti , tí a ti tẹ̀ mọ́lẹ̀ báyìí! “Gbéra, rékọjá lọ sí ọsi, níbẹ̀ pẹ̀lú o kì yóò ní ìsinmi.” Bojú wo ilẹ̀ àwọn ará , àwọn ènìyàn tí kò jámọ́ nǹkan kan báyìí. Àwọn ti sọ ọ́ di ibùgbé àwọn ohun ẹranko aginjù; wọn ti gbé ilé ìṣọ́ ìtẹ̀gùn wọn sókè, wọ́n ti tú odi rẹ̀ sí ìhòhò wọ́n sì ti sọ ọ́ di ààtàn. Hu, ìwọ ọkọ̀ ojú omi ṣiṣi; wọ́n ti pa odi rẹ̀ run! Ní àkókò náà a ó gbàgbé fún àádọ́rin ọdún, ọjọ́ ayé ọba kan. Ṣùgbọ́n ní òpin àádọ́rin ọdún wọ̀nyí, yóò ṣẹlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí orin àgbèrè: “Mú dùùrù kan, rìn kọjá láàrín ìlú, ìwọ àgbèrè tí a ti gbàgbé; lu dùùrù dáradára, kọ ọ̀pọ̀ orin, kí a lè ba à rántí rẹ.” Ní òpin àádọ́rin ọdún náà, Olúwa yóò bá jà. Òun yóò sì padà sí àyálò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí panṣágà, yóò sì máa ṣe òwò rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ilẹ̀ ọba tí ó wà ní ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀síbẹ̀ èrè rẹ̀ àti owó iṣẹ́ rẹ̀ ni a ó yà sọ́tọ̀ fún Olúwa; a kò ní kó wọn pamọ́ tàbí kí a há wọn mọ́wọ́. Ère rẹ̀ ni a ó fi fún àwọn tí ó ń gbé níwájú Olúwa, fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oúnjẹ àti aṣọ.

Every verse in Isaiah 23

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00