Isaiah 31:2

“Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi.”

Isaiah 31:2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 2 of 9 in Isaiah chapter 31 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 31 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ègbé ni fún àwọn tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sí fún ìrànlọ́wọ́, tí wọn gbẹ́kẹ̀lé ẹṣin tí wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́-ẹṣin wọn àti agbára ńlá àwọn ẹlẹ́ṣin wọn, ṣùgbọ́n tiwọn kò bojú wo Ẹni Mímọ́ ẹli n nì, tàbí kí wọn wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Olúwa. Síbẹ̀síbẹ̀ òun pẹ̀lú jẹ́ ọlọ́gbọ́n ó sì lè mú ìparun wá; òun kì í kó ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ. Òun yóò dìde sí ilé àwọn ìkà, àti sí àwọn tí ń ṣe ìrànlọ́wọ́ fún aṣebi. Ṣùgbọ́n ènìyàn lásán ni àwọn ará wọn kì í ṣe Ọlọ́run; ẹran-ara ni àwọn ẹṣin wọn, kì í ṣe ẹ̀mí. Nígbà tí Olúwa bá na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ẹni náà tí ó ń ṣèrànwọ́ yóò kọsẹ̀, ẹni náà tí à ń ràn lọ́wọ́ yóò ṣubú; àwọn méjèèjì yóò sì jùmọ̀ parun. Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún mi: “Gẹ́gẹ́ bí i kìnnìún ti í ké àní kìnnìún ńlá lórí ẹran ọdẹ rẹ̀ bí a tilẹ̀ rí ẹgbẹ́ àwọn olùṣọ́-àgùntàn tí a sì pè wọ́n papọ̀ láti kojú rẹ̀, ẹ̀rù kò lè bà á pẹ̀lú igbe wọn akitiyan wọn kò sì lè dí i lọ́wọ́ bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sọ̀kalẹ̀ wá láti jagun lórí òkè àti lórí ibi gíga rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹyẹ ti ń rábàbà lókè Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò dáàbò bo ẹmu, Òun yóò dáàbò bò ó, yóò sì tú u sílẹ̀ Òun yóò ré e kọjá yóò sì gbà á sílẹ̀.” Ẹ padà sọ́dọ̀ ẹni tí ẹ ti ṣọ̀tẹ̀ sí gidigidi, ẹ̀yin ọmọ ẹli. Nítorí ní ọjọ́ náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò kọ àwọn ère fàdákà àti wúrà tí ọwọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín ti ṣe. “Asiria yóò ṣubú lọ́wọ́ idà kan tí kò ti ọwọ́ ènìyàn wá; idà tí kì í ṣe ti ẹ̀dá alààyè ni yóò pa wọ́n. Wọn yóò sì sá níwájú idà náà àti àwọn ọmọkùnrin wọn ni a ó fún ní iṣẹ́ ipá ṣe. Àpáta rẹ yóò kọjá lọ fún ẹ̀rù; àwọn olórí rẹ yóò bẹ̀rù náà,” ni Olúwa wí, ẹni tí iná rẹ̀ ń bẹ ní , ẹni tí ìléru rẹ̀ wà ní ẹmu.

Every verse in Isaiah 31

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00