Isaiah 35:6
“Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀.”
Isaiah 35:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 6 of 10 in Isaiah chapter 35 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Isaiah 35 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Aginjù àti ìyàngbẹ ilẹ̀ yóò yọ̀ fún wọn; aginjù yóò ṣe àjọyọ̀ yóò sì kún fún ìtànná. Gẹ́gẹ́ bí ewéko, ní títanná yóò tanná; yóò yọ ayọ̀ ńlá ńlá yóò sì kọrin. Ògo ni a ó fi fún un, ẹwà àti Ṣaroni; wọn yóò rí ògo Olúwa, àti ẹwà Ọlọ́run wa. Fún ọwọ́ àìlera lókun, mú orúnkún tí ń yẹ̀ lókun. Sọ fún àwọn íbẹ̀rù ọkàn pé, “Ẹ ṣe gírí, ẹ má bẹ̀rù; Ọlọ́run yín yóò wá, òun yóò wá pẹ̀lú ìgbẹ̀san; pẹ̀lú ìgbẹ̀san mímọ́ òun yóò wá láti gbà yín là.” Nígbà náà ni a ó la ojú àwọn afọ́jú àti etí àwọn odi kì yóò dákẹ́. Nígbà náà ni àwọn arọ yóò máa fò bí àgbọ̀nrín, àti ahọ́n odi yóò ké fún ayọ̀. Odò yóò tú jáde nínú aginjù àti àwọn odò nínú aṣálẹ̀. Ilẹ̀ iyanrìn yíyan yóò di àbàtà, ilẹ̀ tí ń pòǹgbẹ yóò di orísun omi. Ní ibùgbé àwọn dragoni, níbi tí olúkúlùkù dùbúlẹ̀, ni ó jẹ́ ọgbà fún eèsún àti papirusi. Àti òpópónà kan yóò wà níbẹ̀: a ó sì máa pè é ní ọ̀nà ìwà mímọ́. Àwọn aláìmọ́ kì yóò tọ ọ̀nà náà; yóò sì wà fún àwọn tí ń rìn ní ọ̀nà náà, àwọn ìkà búburú kì yóò gba ibẹ̀ kọjá. Kì yóò sí kìnnìún níbẹ̀, tàbí kí ẹranko búburú kí ó dìde lórí i rẹ̀; a kì yóò rí wọn níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn ẹni ìràpadà nìkan ni yóò rìn níbẹ̀, àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ wá pẹ̀lú orin; ayọ̀ ayérayé ni yóò dé wọn ní orí. Ìdùnnú àti ayọ̀ ni yóò borí i wọn, ìkorò àti ìtìjú yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ wọn.
Every verse in Isaiah 35
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.