Isaiah 36:5

“Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi?”

Isaiah 36:5 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 5 of 22 in Isaiah chapter 36 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Isaiah 36 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ọdún kẹrìnlá ìjọba , Sennakeribu ọba kọlu gbogbo àwọn ìlú olódi ní ilẹ̀ ó sì kó gbogbo wọn. Lẹ́yìn náà, ọba rán olórí ogun rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọmọ-ogun láti ṣi sí ọba ní ẹmu. Nígbà tí ọ̀gágun náà dúró níbi ojúṣàn adágún ti apá òkè, ní ojú ọ̀nà sí pápá alágbàfọ̀, Ṣebna ọmọ alábojútó ààfin, Ṣebna akọ̀wé, àti ọmọ akọ̀wé jáde lọ pàdé rẹ̀. Ọ̀gágun náà sọ fún wọn wí pé, “Ẹ sọ fún , “ ‘Èyí yìí ni ohun tí ọba ńlá, ọba sọ pé: Lórí i kí ni ìwọ gbé ìgbẹ́kẹ̀lé tìrẹ yìí lé? Ìwọ sọ wí pé ìwọ ní ète àti agbára ogun—ṣùgbọ́n ìwọ ń sọ ọ̀rọ̀ asán. Ta ni ìwọ gbẹ́kẹ̀lé tí ìwọ fi ṣọ̀tẹ̀ sí mi? Wò ó nísinsin yìí, ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀rún igi ọ̀pá lásán tí í gún ni lọ́wọ́ tí í sì í dọ́gbẹ́ sí ni lára tí a bá gbára lé e! Bẹ́ẹ̀ ni ọba sí àwọn tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e. Bí o bá sì sọ fún mi pé, “Àwa gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run wa,” kì í ṣe òun ni ti mú àwọn ibi gíga àti pẹpẹ rẹ̀ kúrò, tí ó sì wí fún àti ẹmu pé, “Ẹ̀yin gbọdọ̀ sìn níwájú pẹpẹ yìí”? “ ‘Ẹ wá nísinsin yìí, bá ọ̀gá mi pa ìmọ̀ pọ̀, ọba , èmi yóò fún ọ ní ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) ẹṣin bí ìwọ bá le è fi agẹṣin lé wọn lórí! Báwo ni ẹ ṣe lè lé ẹyọ kan ṣoṣo padà nínú èyí tí ó kéré jù nínú àwọn balógun olúwa mi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ gbẹ́kẹ̀lé fún kẹ̀kẹ́-ẹṣin àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síwájú sí i, ǹjẹ́ mo wa lè wá bá ilẹ̀ yìí jà kí n sì pa á run láìsí Olúwa? Olúwa fún rara rẹ̀ ló sọ pé kí n bá orílẹ̀-èdè yìí jà kí n sì pa á run.’ ” Lẹ́yìn náà ni , Ṣebna àti sọ fún ọ̀gágun náà pé, “Jọ̀wọ́ máa bá àwọn ìránṣẹ́ rẹ sọ̀rọ̀ ní èdè , nítorí pé àwa gbọ́ ọ. Má ṣe bá wa sọ̀rọ̀ ní èdè ní etí àwọn ènìyàn tí ó wà lórí ògiri mọ́.” Ṣùgbọ́n aláṣẹ dáhùn pé, “Ṣé fún ọ̀gá rẹ àti ìwọ nìkan ní ọ̀gá mi rán mi sí láti sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí kì í sì í ṣe fún àwọn ọkùnrin tí ó jókòó lórí odi ni gẹ́gẹ́ bí ìwọ, ni yóò ní láti jẹ ìgbẹ́ ará wọn kí wọ́n sì mu ìtọ̀ ará wọn?” Lẹ́yìn náà ni ọ̀gágun náà dìde tí ó sì ké síta ní èdè pé, “Ẹ gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ọba ńlá, ọba ! Ohun tí ọba wí nìyìí, Ẹ má ṣe jẹ́ kí tàn yín jẹ. Òun kò le è gbà yín sílẹ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ kí rọ̀ yín láti gbẹ́kẹ̀lé Olúwa nígbà tí ó sọ pé, ‘Olúwa yóò kúkú gbà wá; a kì yóò fi ìlú yìí lé ọba lọ́wọ́.’ “Ẹ má ṣe tẹ́tí sí . Ohun tí ọba wí nìyìí. Ẹ fi ẹ̀bùn bá mi rẹ́, kí ẹ sì jáde tọ̀ mí wá. Lẹ́yìn náà, ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yóò sì jẹ nínú àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni yóò sì mu omi nínú kànga rẹ̀, títí tí èmi yóò fi mú un yín lọ sí ilẹ̀ kan tí ó dàbí i tiyín, ilẹ̀ tí ó ní irúgbìn íhóró àti wáìnì tuntun, ilẹ̀ tí ó ní àkàrà àti ọgbà àjàrà. “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ṣì yín lọ́nà nígbà tí ó sọ wí pé, ‘Olúwa yóò gbà wá.’ Ǹjẹ́ ọlọ́run orílẹ̀-èdè kan ha ti gbà á kúrò lọ́wọ́ ọba bí? Níbo ni àwọn òrìṣà àti ha wà? Níbo ni àwọn òrìṣà ha wà? Ǹjẹ́ wọn ti já gbà kúrò lọ́wọ́ mi bí? Èwo nínú àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè wọ̀nyí ló ha ti dáàbò bo ilẹ̀ ẹ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ mi? Báwo ni Olúwa ṣe wá le gba ẹmu kúrò lọ́wọ́ mi?” Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn náà dákẹ́ rọ́rọ́ wọn kò sì mú èsì kankan wá, nítorí ọba ti pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ má ṣe dá a lóhùn.” Lẹ́yìn náà ni ọmọ alákòóso ààfin, Ṣebna akọ̀wé àti ọmọ akọ̀wé àkọsílẹ̀ lọ sí ọ̀dọ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn ní fífàya, wọ́n sì sọ ohun tí ọ̀gágun ti wí.

Every verse in Isaiah 36

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00