Isaiah 4:6
“Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.”
Isaiah 4:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 6 of 6 in Isaiah chapter 4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Isaiah 4 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ní ọjọ́ náà, obìnrin méje yóò dì mọ́ ọkùnrin kan yóò sì wí pé, “Àwa ó máa jẹ oúnjẹ ara wa a ó sì pèsè aṣọ ara wa; sá à jẹ́ kí a máa fi orúkọ rẹ̀ pè wá. Mú ẹ̀gàn wa kúrò!” Ní ọjọ́ náà, ẹ̀ka Olúwa yóò ní ẹwà àti ògo, èso ilẹ̀ náà yóò sì jẹ́ ìgbéraga àti ògo àwọn ti ó sálà ní ẹli. Àwọn tí ó ṣẹ́kù ní , àwọn tí o kù ní ẹmu, ni a ó pè ní mímọ́, orúkọ àwọn ẹni tí a kọ mọ́ àwọn alààyè ní ẹmu. Olúwa yóò wẹ ẹ̀gbin àwọn obìnrin kúrò yóò sì fọ gbogbo àbàwọ́n ẹ̀jẹ̀ kúrò ní ẹmu pẹ̀lú ẹ̀mí ìdájọ́ àti ẹ̀mí iná. Lẹ́yìn náà, Olúwa yóò dá sórí òkè àti sórí i gbogbo àwọn tí ó péjọpọ̀ síbẹ̀, kurukuru èéfín ní ọ̀sán àti ìtànṣán ọ̀wọ́-iná ní òru, lórí gbogbo ògo yìí ni ààbò yóò wà. Èyí ni yóò jẹ́ ààbò àti òjìji kúrò lọ́wọ́ ooru ọ̀sán, àti ààbò òun ibi ìsádi kúrò lọ́wọ́ ìjì àti òjò.
Every verse in Isaiah 4
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.