Jeremiah 40:15
“Nígbà náà ni Johanani ọmọkùnrin Karea sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún Gedaliah ní Mispa pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù Juda sì parun?””
Jeremiah 40:15 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 15 of 16 in Jeremiah chapter 40 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Jeremiah 40 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ọ̀rọ̀ náà sì tọ wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa lẹ́yìn tí balógun àwọn ẹ̀ṣọ́ ti tú u sílẹ̀ ní . Ó rí tí a fi ẹ̀wọ̀n dè láàrín gbogbo àwọn tí wọ́n mú ní ẹmu àti . Wọ́n kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì . Nígbà tí balógun ẹ̀ṣọ́ rí , ó sọ fún un wí pé, “Olúwa Ọlọ́run rẹ ni ó pàṣẹ ibí yìí fún mi. Nísinsin yìí, Olúwa ti mú un jáde; ó ti ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ pé òun yóò ṣe. Gbogbo èyí ṣẹlẹ̀ nítorí wí pé ẹ̀yin ènìyàn ṣẹ̀ sí Olúwa, àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, ní òní yìí mò ń tú ọ sílẹ̀ kúrò nínú ẹ̀wọ̀n tí ó wà ní ọwọ́ rẹ. Bí o bá fẹ́, tẹ̀lé mi ká lọ sí , èmi yóò sì bojútó ọ; ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá fẹ́, dúró síbí. Wò ó, gbogbo orílẹ̀-èdè wà níwájú rẹ, lọ sí ibikíbi tí ó bá tẹ́ ọ lọ́rùn.” Ẹ̀wẹ̀, kí ó tó di pé pẹ̀yìndà láti máa lọ, Nebusaradani fi kún un wí pé, “Padà tọ ọmọ lọ, ọmọ Ṣafani, ẹni tí ọba ti fi jẹ baálẹ̀ lórí ìlú , kí o sì máa gbé ní àárín àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o máa lọ ibikíbi tí ó bá tọ́ ní ojú rẹ.” Nígbà náà ni balógun náà fún un ní oúnjẹ àti ẹ̀bùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ. Báyìí ni lọ sí ọ̀dọ̀ ọmọkùnrin ní , ó sì dúró tì í láàrín àwọn ènìyàn tí ó ṣẹ́kù ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ènìyàn tí wọ́n kù lórí orílẹ̀-èdè náà gbọ́ pé ọba ti yan ọmọkùnrin gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀ ní ilẹ̀ náà; àti pé ó ti fi àwọn ọkùnrin, obìnrin àti ọmọdé tí wọ́n jẹ́ tálákà ní ilẹ̀ náà tí wọn kò kó lọ sí ilẹ̀ àjèjì sí ìkáwọ́ rẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ ní ; Iṣmaeli ọmọkùnrin , Johanani àti ọmọkùnrin ti , Seraiah ọmọkùnrin tí í ṣe ọmọkùnrin ará àti ọmọkùnrin àti àwọn ènìyàn wọn. Gedaliah ọmọkùnrin , ọmọkùnrin ti Ṣafani ṣe ìbúra láti tún fi dá àwọn ènìyàn lójú pé, “Ẹ má ṣe bẹ̀rù láti sin àwọn .” Ó sọ wí pé, “Gbé ilẹ̀ náà kí ẹ sì máa sin ọba , yóò sì dára fún un yín. Èmi fúnra mi yóò dúró ní láti ṣojú yín níwájú tí wọ́n tọ̀ wá wá. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ni yóò máa kórè ọtí wáìnì, èso igi àti òróró; kí ẹ sì kó wọn sí inú àpò àpamọ́wọ́ yín; kí ẹ̀yin sì máa gbé ní ìlú tí ẹ ti gbà.” Nígbà tí gbogbo àwọn ní , Ammoni, Edomu àti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè gbọ́ pé ọba ti fi ohun tókù sílẹ̀ ní , àti pé ó ti yan ọmọkùnrin ọmọkùnrin Ṣafani gẹ́gẹ́ bí gómìnà lórí wọn. Gbogbo wọn padà wá sí ilẹ̀ sọ́dọ̀ ní láti orílẹ̀-èdè gbogbo tí a ti lé wọn sí. Wọ́n sì kórè ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọtí wáìnì àti èso igi. Johanani ọmọkùnrin ti àti gbogbo àwọn olórí ogun tí ó kù ní orílẹ̀-èdè sì tọ wá ní . Wọ́n sì sọ fún un wí pé, “Ǹjẹ́ ìwọ ha mọ̀ pé ọba àwọn ti rán Iṣmaeli ọmọkùnrin láti lọ mú ẹ̀mí rẹ?” Ṣùgbọ́n ọmọkùnrin ti kò gbà wọ́n gbọ́. Nígbà náà ni ọmọkùnrin sọ ní ìkọ̀kọ̀ fún ní pé, “Jẹ́ kí èmi lọ pa Iṣmaeli ọmọkùnrin , ẹnikẹ́ni kò sì ní mọ èyí. Kí ni ìdí rẹ̀ tí yóò ṣe mú ẹ̀mí rẹ, tí o sì ṣe fẹ́ mú àwọn Júù tí ó yí ọ ká túká, kí ìyókù sì parun?” Ṣùgbọ́n ọmọ sọ fún ọmọ pé, “Má ṣe ṣe nǹkan yìí! Nítorí nǹkan tí ò ń sọ nípa Iṣmaeli kì í ṣe òtítọ́.”
Every verse in Jeremiah 40
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.