Jeremiah 46:7
““Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò Ejibiti, tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì?”
Jeremiah 46:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 7 of 28 in Jeremiah chapter 46 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Jeremiah 46 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó tọ wòlíì wá nípa àwọn Orílẹ̀-èdè. Nípa . Èyí ni ọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ-ogun ọba ẹni tí a borí rẹ̀ ní ṣi, ní odò láti ọwọ́ ọba ní ọdún kẹrin ọmọ ọba : “Ẹ múra àpáta, èyí tí ó tóbi, àti èyí tí ó kéré, kí ẹ sì súnmọ́ ojú ìjà! Ẹ di ẹṣin ní gàárì, kí ẹ sì gùn ún. Ẹ dúró lẹ́sẹẹsẹ pẹ̀lú àṣíborí yín! Ẹ dán ọ̀kọ̀ yín, kí ẹ sì wọ ẹ̀wù irin. Kí ni nǹkan tí mo tún rí? Wọ́n bẹ̀rù, wọ́n sì ń padà sẹ́yìn, wọ́n ti ṣẹ́gun àwọn jagunjagun. Wọ́n sá, wọn kò sì bojú wẹ̀yìn, ìbẹ̀rù sì wà níbi gbogbo,” ni Olúwa wí. “Ẹni tí ó yára kì yóò le sálọ, tàbí alágbára kò ní lè sá àsálà. Ní àríwá ní ibi odò wọn yóò kọsẹ̀, wọn yóò sì ṣubú. “Ta ni èyí tí ó gòkè wá bí odò , tí omi rẹ̀ ń ru gẹ́gẹ́ bí odò wọ̀n-ọn-nì? Ejibiti dìde bí odò náà, bí omi odò tí ń ru. Ó sì wí pé, ‘Èmi yóò dìde, n ó sì bo gbogbo ilẹ̀ ayé.’ Èmi yóò pa ìlú àti àwọn ènìyàn rẹ̀ run. Ẹ gòkè wá ẹ̀yin ẹṣin, ẹ sì sáré kíkankíkan ẹ̀yin kẹ̀kẹ́. Kí àwọn alágbára túbọ̀ tẹ̀síwájú, àwọn ará Kuṣi àti àwọn ará tí ń di asà mú; àti àwọn ará tí ń fa ọrun. Ṣùgbọ́n ọjọ́ náà jẹ́ ti Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ọjọ́ ìgbẹ̀san, ìgbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀. Idà yóò sì jẹ́ títí yóò fi ní ìtẹ́lọ́rùn, títí yóò fi pa òǹgbẹ rẹ̀ rẹ́ pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀. Nítorí pé Olúwa, Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò rú ẹbọ ní ilẹ̀ gúúsù ní odò . “Gòkè lọ sí , kí o sì mú ìkunra, ìwọ wúńdíá ọmọbìnrin . Ṣùgbọ́n ní asán ni ìwọ ń lo oògùn, kì yóò sí ìwòsàn fún ọ. Àwọn orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ nípa ìtìjú rẹ, igbe rẹ yóò kún gbogbo ayé. Jagunjagun yóò máa ṣubú lu ara wọn lórí rẹ, àwọn méjèèjì yóò sì jọ ṣubú papọ̀.” Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó bá wòlíì nì sọ nípa wíwá ọba láti lọ dojú ìjà kọ : “Kéde èyí ní , sì sọ ọ́ ní , sọ ọ́ ní àti : ‘Dúró sí ààyè rẹ kí o sì múra sílẹ̀, nítorí pé idà náà ń pa àwọn tí ó yí ọ ká.’ Èéṣe tí àwọn akọni rẹ fi ṣubú? Wọn kò ní le dìde dúró, nítorí Olúwa yóò tì wọ́n ṣubú. Wọn yóò máa ṣubú léraléra wọn yóò máa ṣubú lu ara wọn. Wọn yóò sọ wí pé, ‘Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn wa àti ilẹ̀ ìbí wa, kúrò níbi idà àwọn aninilára.’ Níbẹ̀ ni wọn ó kígbe pé, ‘Ariwo lásán ni ọba pa, ó ti sọ àǹfààní rẹ̀ nù.’ “Bí èmi ti wà láààyè,” ni ọba, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Nítòótọ́ gẹ́gẹ́ bí láàrín àwọn òkè àti gẹ́gẹ́ bi lẹ́bàá Òkun bẹ́ẹ̀ ni òun yóò dé. Ìwọ, ọmọbìnrin ti ń gbé pèsè ohun èlò ìrìnàjò fún ara rẹ nítorí yóò di ahoro a ó sì fi jóná, láìní olùgbé. “Ẹgbọrọ abo màlúù tó lẹ́wà ní ṣùgbọ́n eṣinṣin ìparun dé, ó dé láti àríwá. Àwọn jagunjagun rẹ̀ dàbí àbọ́pa akọ màlúù. Àwọn pẹ̀lú yóò yípadà, wọn ó sì jùmọ̀ sá, wọn kò ní le dúró, nítorí tí ọjọ́ ibi ń bọ̀ lórí wọn àsìkò láti jẹ wọ́n ní ìyà. Ejibiti yóò pòṣé bí ejò tí ń sá bí ọmọ-ogun ṣe ń tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú agbára. Wọn ó tọ̀ ọ́ wá pẹ̀lú àáké, gẹ́gẹ́ bí i ti agégi. Wọn o gé igbó rẹ̀ lulẹ̀,” ni Olúwa wí, “nítorí ti a kò le rídìí rẹ̀. Nítorí pé wọ́n pọ̀ ju ẹlẹ́ǹgà lọ, wọ́n sì jẹ́ àìníye. A ó dójútì ọmọbìnrin , a ó fà á lé ọwọ́ àwọn ènìyàn àríwá.” Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run ẹli wí pé: “Èmi yóò rọ̀jò ìyà mi sórí òrìṣà , sórí , sórí àti àwọn òrìṣà rẹ̀ àti sórí àwọn ọba rẹ̀ àti sórí àwọn tó gbẹ́kẹ̀lé . Èmi ó sì fi wọ́n lé àwọn tó wá ẹ̀mí wọn lọ́wọ́, lé ọba , ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, Ejibiti yóò sì di gbígbé bí i ti àtijọ́,” ni Olúwa wí. “Má bẹ̀rù, ìwọ ọbu ìránṣẹ́ mi, má fòyà, ìwọ ẹli. Dájúdájú èmi ó gbà ọ́ láti ọ̀nà jíjìn, àwọn ọmọ ọmọ rẹ ní ilẹ̀ ìgbèkùn. Jakọbu yóò tún ní àlàáfíà àti ààbò, kò sì ṣí ẹni tí yóò dẹ́rùbà á. Má bẹ̀rù, Jakọbu ìránṣẹ́ mi, nítorí pé mo wà pẹ̀lú rẹ,” bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí. “Bí mo tilẹ̀ pa gbogbo orílẹ̀-èdè run, láàrín àwọn tí mo fọ́n yín ká sí. Èmi kò ní run yín tán. Èmi yóò jẹ ọ́ ní ìyà lórí òdodo, èmi kí yóò jọ̀wọ́ rẹ lọ́wọ́ lọ láìjẹ ọ́ ní yà.”
Every verse in Jeremiah 46
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.