Jeremiah 48:18

““Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni, nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.”

Jeremiah 48:18 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 18 of 47 in Jeremiah chapter 48 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Jeremiah 48 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nípa . Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run ẹli wí: “Ègbé ni fún nítorí a ó parun. A dójútì , a sì mú un, ojú yóò ti alágbára, a ó sì fọ́nká. Moabu kò ní ní ìyìn mọ́, ní Heṣboni ni wọn ó pète ìparun rẹ̀, ‘Wá, kí a pa orílẹ̀-èdè náà run.’ Àti ẹ̀yin òmùgọ̀ ọkùnrin pàápàá ni a ó pa lẹ́nu mọ́, a ó fi idà lé e yín. Gbọ́ igbe ní , igbe ìrora àti ìparun ńlá. Moabu yóò di wíwó palẹ̀; àwọn ọmọdé rẹ̀ yóò kígbe síta. Wọ́n gòkè lọ sí , wọ́n ń sọkún kíkorò bí wọ́n ti ń lọ; ní ojú ọ̀nà sí igbe ìrora ìparun ni à ń gbọ́ lọ. Sá! Àsálà fún ẹ̀mí yín; kí ẹ sì dàbí aláìní ní aginjù. Níwọ́n ìgbà tí o gbẹ́kẹ̀lé agbára àti ọrọ̀ rẹ, a ó kó ìwọ náà ní ìgbèkùn, Kemoṣi náà yóò lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn pẹ̀lú àlùfáà àti àwọn aláṣẹ rẹ̀. Gbogbo ìlú rẹ ni apanirun yóò dojúkọ, ìlú kan kò sì ní le là. Àfonífojì yóò di ahoro àti ilẹ̀ títẹ́ ni a ó run, nítorí tí Olúwa ti sọ̀rọ̀. Fi iyọ̀ sí , nítorí yóò ṣègbé, àwọn ìlú rẹ yóò sì di ahoro láìsí ẹni tí yóò gbé inú rẹ̀. “Ìfibú ni fún ẹni tí ó fi ìmẹ́lẹ́ ṣe iṣẹ́ Olúwa, ìfibú ni fún ẹni tí ó pa idà mọ́ fún ìtàjẹ̀ sílẹ̀. “Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀, tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí. Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ, òórùn rẹ̀ kò yí padà. Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí, “nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò tí wọ́n ó sì dà á síta; wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo, wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀. Nígbà náà yóò sì tú u nítorí ṣi, bí ojú ti í ti ilé ẹli nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé . “Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá, alágbára ní ogun jíjà’? A ó pa run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀; a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,” ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. “Ìṣubú súnmọ́; ìpọ́njú yóò dé kánkán. Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó. Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’ “Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ, kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ, ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin , nítorí tí ẹni tí ó pa run yóò dojúkọ ọ́ yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run. Dúró lẹ́bàá ọ̀nà kí o sì wòran, ìwọ tí ń gbé ní . Bí ọkùnrin tí ó sálọ àti obìnrin tí ó ń sá àsálà ‘Kí ni ohun tí ó ṣẹlẹ̀?’ Ojú ti nítorí tí a wó o lulẹ̀. Ẹ hu, kí ẹ sì kígbe! Ẹ kéde rẹ̀ ní pé, a pa run. Ìdájọ́ ti dé sí àwọn òkè pẹrẹsẹ, sórí , Jahisa àti , sórí , Nebo àti -, sórí , Beti- àti -, sórí àti , sórí gbogbo ìlú , nítòsí àti ní ọ̀nà jíjìn. A gé ìwo kúrò, apá rẹ̀ dá,” ni Olúwa wí. “Ẹ jẹ́ kí a mú u mutí nítorí ó kó ìdọ̀tí bá Olúwa, jẹ́ kí lúwẹ̀ẹ́ nínú èébì rẹ̀, kí ó di ẹni ẹ̀gàn. Ǹjẹ́ ẹli kò di ẹni ẹ̀gàn rẹ? Ǹjẹ́ a kó o pẹ̀lú àwọn olè tó bẹ́ẹ̀ tí o ń gbọn orí rẹ̀ pẹ̀lú yẹ̀yẹ́ nígbàkígbà bí a bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Kúrò ní àwọn ìlú rẹ, kí o sì máa gbé láàrín àwọn òkúta, ẹ̀yin tí ó ti ń gbé inú ìlú . Ẹ dàbí i àdàbà tí ó kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ẹnu ihò. “A ti gbọ́ nípa ìgbéraga : àti ìwà mo gbọ́n tan rẹ̀ àti ìgbéraga ọkàn rẹ̀. Mo mọ àfojúdi rẹ̀, ṣùgbọ́n òfo ni,” ni Olúwa wí, “ìfọ́nnu rẹ̀ kò lè ṣe nǹkan kan. Nítorí náà, mo pohùnréré ẹkún lórí fún àwọn ará ni mo kígbe lóhùn rara, mo kẹ́dùn fún àwọn ọkùnrin -. Mo sọkún fún ọ bí ṣe sọkún ìwọ àjàrà . Ẹ̀ka rẹ tẹ̀ títí dé Òkun, wọn dé Òkun . Ajẹnirun ti kọlu èso rẹ, ìkórè èso àjàrà rẹ. Ayọ̀ àti ìdùnnú ti kúrò nínú ọgbà àjàrà àti oko . Mo dá ọwọ́ ṣíṣàn ọtí wáìnì dúró lọ́dọ̀ olùfúntí; kò sí ẹni tí ó ń tẹ̀ wọ́n pẹ̀lú igbe ayọ̀. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé igbe wà, wọn kì í ṣe igbe ti ayọ̀. “Ohùn igbe wọn gòkè láti Heṣboni dé àti , láti títí dé àti -Ṣṣi, nítorí àwọn omi pẹ̀lú yóò gbẹ. Ní ti ni èmi yóò ti fi òpin sí ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,” ni Olúwa wí. “Nítorí náà ọkàn mi ró fún bí fèrè, ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin -. Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé. Gbogbo orí ni yóò pá, gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò, gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́, àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́. Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé , àti ní ìta rẹ̀, nítorí èmi ti fọ́ bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,” ni Olúwa wí. “Èéṣe tí ẹ fi fọ́ túútúú, tí ẹ sì fi ń pohùnréré ẹkún! Báwo ni ṣe yí ẹ̀yìn padà ní ìtìjú! Moabu ti di ẹni ìtìjú àti ẹ̀gàn àti ìdààmú sí gbogbo àwọn tí ó yìí ká.” Báyìí ni Olúwa wí: “Wò ó ẹyẹ idì náà ń fò bọ̀ nílẹ̀ ó sì na ìyẹ́ rẹ̀ lórí . Kerioti ni a ó kó lẹ́rú àti ilé agbára ni ó gbà. Ní ọjọ́ náà ọkàn àwọn akọni yóò dàbí ọkàn obìnrin tí ó ń rọbí. A ó pa run gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè nítorí pé ó gbéraga sí Olúwa. Ẹ̀rù àti ọ̀fìn àti okùn dídè ń dúró dè yín, ẹ̀yin ènìyàn ,” ní Olúwa wí. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá sá fún ẹ̀rù yóò ṣubú sínú ọ̀fìn ẹnikẹ́ni tí o bá jáde síta nínú ọ̀fìn ní à ó mú nínú okùn dídè nítorí tí èmi yóò mú wá sórí àní ọdún ìjìyà rẹ,” ní Olúwa wí. “Ní abẹ́ òjìji Heṣboni àwọn tí ó sá dúró láìní agbára, nítorí iná ti jáde wá láti Heṣboni, àti ọwọ́ iná láti àárín , yóò sì jó iwájú orí run, àti agbárí àwọn ọmọ aláriwo. Ègbé ní fún ọ ! Àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè ṣi ṣègbé a kó àwọn ọmọkùnrin rẹ lọ sí ilẹ̀ àjèjì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ lọ sí ìgbèkùn. “Síbẹ̀, èmi yóò dá ìkólọ padà ní ọjọ́ ìkẹyìn,” ni Olúwa wí. Eléyìí ní ìdájọ́ ìkẹyìn lórí .

Every verse in Jeremiah 48

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00