Job 27:2

““Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́,”

Job 27:2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 2 of 23 in Job chapter 27 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Job 27 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Pẹ̀lúpẹ̀lú sì tún sọkún ọ̀rọ̀ òwe rẹ̀, ó sì wí pé, “Bí Ọlọ́run ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ìdájọ́ mi lọ, àti Olódùmarè tí ó bà mi ní ọkàn jẹ́, níwọ́n ìgbà tí ẹ̀mí mi ń bẹ nínú mi, àti tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń bẹ nínú ihò imú mi. Ètè mi kì yóò sọ̀rọ̀ èké, bẹ́ẹ̀ ni ahọ́n mi kì yóò sọ̀rọ̀ ẹ̀tàn. Kí a má rí i pé èmi ń dá yín láre; títí èmi ó fi kú, èmi kì yóò ṣí ìwà òtítọ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi. Òdodo mi ni èmi dìímú ṣinṣin, èmi kì yóò sì jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́; àyà mi kì yóò sì gan ọjọ́ kan nínú ọjọ́ ayé mi. “Kí ọ̀tá mi kí ó dàbí ènìyàn búburú, àti ẹni tí ń dìde sí mi kí ó dàbí ẹni aláìṣòdodo. Nítorí kí ni ìrètí àgàbàgebè, nígbà tí Ọlọ́run bá ké ẹ̀mí rẹ̀ kúrò, nígbà tí ó sì fà á jáde? Ọlọ́run yóò ha gbọ́ àdúrà rẹ̀, nígbà tí ìpọ́njú bá dé sí i? Òun ha le ní inú dídùn sí Olódùmarè? Òun ha lé máa ké pe Ọlọ́run nígbà gbogbo? “Èmi ó kọ́ yín ní ẹ̀kọ́ ní ti ọwọ́ Ọlọ́run: ọ̀nà tí ń bẹ lọ́dọ̀ Olódùmarè ni èmi kì yóò fi pamọ́. Kíyèsi i, gbogbo yín ni ó ti rí i; kín ni ìdí ọ̀rọ̀ asán yín? “Ẹ̀yin ni ìpín ènìyàn búburú lọ́dọ̀ Ọlọ́run, àti ogún àwọn aninilára, tí wọ́n ó gbà lọ́wọ́ Olódùmarè. Bí àwọn ọmọ rẹ bá di púpọ̀, fún idà ni; àwọn ọmọ ọmọ rẹ̀ kì yóò yó fún oúnjẹ. Àwọn tí ó kù nínú tirẹ̀ ni a ó sìnkú nínú àjàkálẹ̀-ààrùn: àwọn opó rẹ̀ kì yóò sì sọkún fún wọn. Bí ó tilẹ̀ kó fàdákà jọ bí erùpẹ̀, tí ó sì dá aṣọ jọ bí amọ̀; àwọn ohun tí ó tò jọ àwọn olóòtítọ́ ni yóò lò ó; àwọn aláìṣẹ̀ ni yóò sì pín fàdákà rẹ̀. Òun kọ́ ilé rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí kòkòrò aṣọ, àti bí ahéré tí olùṣọ́ kọ́. Ọlọ́rọ̀ yóò dùbúlẹ̀, ṣùgbọ́n òun kì yóò túnṣe bẹ́ẹ̀ mọ́, nígbà tí ó bá la ojú rẹ̀, gbogbo rẹ̀ a lọ. Ẹ̀rù ńlá bà á bí omi ṣíṣàn; ẹ̀fúùfù ńlá jí gbé lọ ní òru. Ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn gbé e lọ, òun sì lọ; àti bí ìjì ńlá ó sì fà á kúrò ní ipò rẹ̀. Nítorí pé Olódùmarè yóò kọlù ú, kì yóò sì dá sí; òun ìbá yọ̀ láti sá kúrò ní ọwọ́ rẹ̀. Àwọn ènìyàn yóò sì ṣápẹ́ sí i lórí, wọn yóò sì ṣe síọ̀ sí i kúrò ní ipò rẹ̀.”

Every verse in Job 27

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00