Jonah 2:7

““Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ.”

Jonah 2:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 7 of 10 in Jonah chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Jonah 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Nígbà náà ni gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ láti inú ẹja náà wá, Ó sì wí pé: “Nínú ìpọ́njú mi ni mo kígbe sí Olúwa, òun sì gbọ́ ohùn mi. Mo kígbe láti inú ipò òkú, mo pè fún ìrànwọ́, ìwọ sì gbọ́ ohùn mi. Nítorí tí ìwọ ti sọ mí sínú ibú, ní àárín Òkun, ìṣàn omi sì yí mi káàkiri; gbogbo bíbì omi àti rírú omi rékọjá lórí mi. Nígbà náà ni mo wí pé, ‘A ta mí nù kúrò níwájú rẹ; ṣùgbọ́n síbẹ̀ èmi yóò tún máa wo ìhà tẹmpili mímọ́ rẹ.’ Omi yí mi káàkiri, àní títí dé ọkàn; ibú yí mi káàkiri, a fi koríko odò wé mi lórí. Èmi sọ̀kalẹ̀ lọ sí ìsàlẹ̀ àwọn òkè ńlá; ilẹ̀ ayé pẹ̀lú ìdènà rẹ̀ yí mi ká títí: ṣùgbọ́n ìwọ ti mú ẹ̀mí mi wá sókè láti inú ibú wá, Olúwa Ọlọ́run mi. “Nígbà tí ó rẹ ọkàn mi nínú mi, èmi rántí rẹ, Olúwa, àdúrà mi sì wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, nínú tẹmpili mímọ́ rẹ. “Àwọn tí ń fàmọ́ òrìṣà èké kọ àánú ara wọn sílẹ̀. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi orin ọpẹ́, rú ẹbọ sí ọ. Èmi yóò san ẹ̀jẹ́ tí mo ti jẹ́. ‘Ìgbàlà wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa.’ ” Olúwa sì pàṣẹ fún ẹja náà, ó sì pọ sí orí ilẹ̀ gbígbẹ.

Every verse in Jonah 2

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00