Joshua 18:10

“Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.”

Joshua 18:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 10 of 28 in Joshua chapter 18 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Joshua 18 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ ẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn, ṣùgbọ́n ó ku ẹ̀yà méje nínú àwọn ọmọ ẹli tí kò tí ì gba ogún ìní wọn. Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ ẹli, “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín? Ẹ yan àwọn ọkùnrin mẹ́ta nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan. Èmi yóò rán wọn jáde láti lọ bojú wo ilẹ̀ náà káàkiri, wọn yóò sì ṣe àpèjúwe rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìní ẹni kọ̀ọ̀kan. Nígbà náà ni wọn yóò padà tọ̀ mí wá. Ẹ̀yin yóò sì pín ilẹ̀ náà sí ọ̀nà méje kí dúró sí ilẹ̀ rẹ̀ ni ìhà gúúsù àti ilé ẹfu ní ilẹ̀ rẹ̀ ní ìhà àríwá. Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà , ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn . Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.” Bí àwọn ọkùnrin náà ti bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn láti fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà, Joṣua pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ lọ kí ẹ sì fojú díwọ̀n ilẹ̀ náà káàkiri, kí ẹ sì kọ àpèjúwe rẹ̀. Lẹ́yìn náà kí ẹ padà tọ̀ mí wá, kí èmi kí ò lè ṣẹ́ kèké fún yin ní ibí ní Ṣilo ní iwájú Olúwa.” Báyìí ni àwọn ọkùnrin náà lọ, wọ́n sì la ilẹ̀ náà já. Wọ́n sì kọ àpèjúwe rẹ̀ sí orí ìwé kíká ní ìlú, ní ọ̀nà méje, wọ́n sì padà tọ Joṣua lọ ní ibùdó ní Ṣilo. Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn ẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀. Ìbò náà sì wá sórí ẹ̀yà , ní agbo ilé, agbo ilé. Ilẹ̀ ìpín wọn sì wà láàrín ti ẹ̀yà àti ẹfu. Ní ìhà àríwá ààlà wọn bẹ̀rẹ̀ ní , ó kọjá lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ ní ìhà àríwá, ó sì forí lé ìwọ̀-oòrùn sí ìlú òkè, jáde sí aginjù -. Láti ibẹ̀ ààlà náà tún kọjá lọ sí ìhà gúúsù ní ọ̀nà (tí í ṣe ) ó sì dé -, ní orí òkè tí ó wà ní gúúsù -. Láti òkè tí ó kọjú sí - ní gúúsù ààlà náà yà sí gúúsù ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, ó sì jáde sí - (tí í ṣe -), ìlú àwọn ènìyàn . Èyí ni ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìhà gúúsù bẹ̀rẹ̀ ní ìpẹ̀kun - ní ìwọ̀-oòrùn, ààlà náà wà ní ibi ìsun omi . Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí àfonífojì -, àríwá àfonífojì . O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí àfonífojì sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú , ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-. Nígbà náà ni ó yípo sí ìhà àríwá, ó sì lọ sí Ẹni-Ṣemeṣi, ó tẹ̀síwájú dé tí ó kọjú sí òkè , ó sì sọ̀kalẹ̀ sí ibi Òkúta ọmọ . Ó tẹ̀síwájú títí dé gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè -, ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí aginjù. Nígbà náà ni ó lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè -, ó sì jáde ní àríwá etí bèbè Òkun Iyọ̀, ní ẹnu odò ní gúúsù. Èyí ni ààlà ti gúúsù. Odò sí jẹ́ ààlà ní ìhà ìlà-oòrùn. Ìwọ̀nyí ní àwọn ààlà ti ó sàmì sí ìní àwọn ìdílé ní gbogbo àwọn àyíká wọn. Ẹ̀yà ní agbo ilé, agbo ilé ni àwọn ìlú wọ̀nyí: Jeriko, Beti-, Emeki-Keṣiṣi, Beti-, Semaraimu, Beteli, Affimu, Para, Ofira Kefari, Ammoni, Ofini àti ; àwọn ìlú méjìlá àti ìletò wọn. Gibeoni, Rama, Beeroti, Mispa, Kefira, Mosa, Rekemu, Irpeeli, Tarala, Ṣela, Haelefi, ìlú (tí í ṣe ẹmu), àti , àwọn ìlú mẹ́rìnlá àti ìletò wọn. Èyí ni ìní fún ìdílé rẹ̀.

Every verse in Joshua 18

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00