Lamentations 2:9

“Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́.”

Lamentations 2:9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 9 of 22 in Lamentations chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Lamentations 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Báwo ni Olúwa ṣe bo ọmọbìnrin pẹ̀lú àwọsánmọ̀ ìbínú rẹ̀! Ó sọ ògo ẹli kalẹ̀, láti ọ̀run sí ayé; kò rántí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ní ọjọ́ ìbínú rẹ̀. Láìní àánú ni Olúwa gbé ibùgbé ọbu mì; nínú ìrunú rẹ̀, ni ó wó ibi gíga ọmọbìnrin lulẹ̀. Ó ti mú ìjọba àti àwọn ọmọ-aládé ọkùnrin lọ sínú ilẹ̀ ní àìlọ́wọ̀. Ní ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó ké gbogbo ìwo ẹli. Ó ti mú ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ kúrò nígbà tí àwọn ọ̀tá dé. Ó run ní ọbu bí ọ̀wọ́-iná ní àgọ́ àwọn ọmọbìnrin . Ó na ọfà rẹ̀ bí ọ̀tá; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ sì múra. Bí ti ọ̀tá tí ó ti parun ó tú ìbínú rẹ̀ jáde bí iná sórí àgọ́ ọmọbìnrin . Olúwa dàbí ọ̀tá; ó gbé ẹli mì. Ó ti gbé gbogbo ààfin rẹ̀ mì ó pa ibi gíga rẹ̀ run. Ó sọ ìmí ẹ̀dùn àti ìbànújẹ́ di púpọ̀ fún àwọn ọmọbìnrin . Ó mú ìparun bá ibi mímọ́, ó pa ibi ìpàdé rẹ̀ run. Olúwa ti mú gbàgbé àjọ̀dún tí a yàn àti ọ̀sẹ̀ tí ó yàn; nínú ìbínú gbígbóná rẹ̀ ni ó run ọba àti olórí àlùfáà. Olúwa ti kọ̀ pẹpẹ rẹ̀ sílẹ̀ ó sì ti kọ̀ ibi mímọ́ rẹ̀. Ó sì fi lé ọ̀tá lọ́wọ́ àwọn odi ààfin rẹ̀; wọ́n sì kígbe ní ilé Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ àpèjẹ tí a yàn. Olúwa pinnu láti fa ògiri tí ó yí ọmọbìnrin ya. Ó gbé wọn sórí òsùwọ̀n, kò sì fa ọwọ́ rẹ̀ padà kúrò nínú ìparun wọn. Ó mú kí ilé ìṣọ́ àti odi rẹ̀ ṣọ̀fọ̀ wọ́n ṣòfò papọ̀. Ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ ti wọ inú ilẹ̀; òpó rẹ̀ ni ó wó tí ó sì ti bàjẹ́. Ọba àti ọmọ ọbakùnrin rẹ̀ wà ní ìgbèkùn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, kò sí òfin mọ́, àwọn wòlíì rẹ̀ kò rí ìran láti ọ̀dọ̀ Olúwa mọ́. Àwọn àgbàgbà ọmọbìnrin jókòó sílẹ̀ ní ìdákẹ́rọ́rọ́; wọ́n da eruku sí orí wọn wọ́n sì wọ aṣọ àkísà. Àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin ẹmu ti tẹrí wọn ba sí ilẹ̀. Ojú mi kọ̀ láti sọkún, mo ń jẹ ìrora nínú mi, mo tú ọkàn mi jáde sí ilẹ̀ nítorí a pa àwọn ènìyàn mí run, nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ ọwọ́ ń kú ní òpópó ìlú. Wọ́n wí fún àwọn ìyá wọn, “Níbo ni ọkà àti wáìnì wà?” Wò ó bí wọ́n ṣe ń kú lọ bí àwọn ọkùnrin tí a ṣe léṣe ní àwọn òpópónà ìlú, bí ayé wọn ṣe ń ṣòfò láti ọwọ́ ìyá wọn. Kí ni mo le sọ fún ọ? Pẹ̀lú kí ni mo lè fi ọ́ wé, ìwọ ọmọbìnrin ẹmu? Kí sì ni mo lè fi ọ́ wé, kí n lè tù ọ́ nínú, ìwọ wúńdíá obìnrin ? Ọgbẹ́ rẹ jì bí Òkun. Ta ni yóò wò ọ́ sàn? Ìran àwọn wòlíì rẹ jẹ́ kìkì ẹ̀tàn láìní ìwọ̀n; wọn kò sì fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ hàn tí yóò mú ìgbèkùn kúrò fún ọ. Àwọn òrìṣà tí wọ́n fún ọ jẹ́ èké àti ìmúniṣìnà. Àwọn tí ó gba ọ̀nà ọ̀dọ̀ rẹ pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí; wọ́n kẹ́gàn wọ́n ju orí wọn sí ọmọbìnrin ẹmu: “Èyí ha ni ìlú tí à ń pè ní àṣepé ẹwà, ìdùnnú gbogbo ayé?” Gbogbo àwọn ọ̀tá rẹ la ẹnu wọn gbòòrò sí ọ; wọ́n kẹ́gàn, wọ́n sì payínkeke wọ́n wí pé, “A ti gbé e mì tán. Èyí ni ọjọ́ tí a ti ń retí; tí a sì wá láti rí.” Olúwa ti ṣe ohun tí ó pinnu; ó ti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ, tí ó sì pàṣẹ ní ọjọ́ pípẹ́. Ó ti ṣí ọ ní ipò láì láàánú, ó fún ọ̀tá ní ìṣẹ́gun lórí rẹ, ó ti gbé ìwo àwọn ọ̀tá rẹ̀ ga. Ọkàn àwọn ènìyàn kígbe jáde sí Olúwa. Odi ọmọbìnrin , jẹ́ kí ẹkún rẹ̀ sàn bí odò ní ọ̀sán àti òru; má ṣe fi ara rẹ fún ìtura, ojú rẹ fún ìsinmi. Dìde, kígbe sókè ní àṣálẹ́, bí ìṣọ́ òru ti bẹ̀rẹ̀ tú ọkàn rẹ̀ jáde bí omi níwájú Olúwa. Gbé ọwọ́ yín sókè sí i nítorí ẹ̀mí àwọn èwe rẹ̀ tí ó ń kú lọ nítorí ebi ní gbogbo oríta òpópó. “Wò ó, Olúwa, kí o sì rò ó. Ta ni ìwọ ti fìyà jẹ bí èyí. Ǹjẹ́ àwọn obìnrin yóò ha jẹ ọmọ wọn, àwọn ọmọ tí wọn ń ṣe ìtọ́jú fún? Ǹjẹ́ kí a pa olórí àlùfáà àti àwọn wòlíì ní ibi mímọ́ Olúwa? “Ọmọdé àti àgbà ń sùn papọ̀ sínú eruku àwọn òpópó; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin mi ti ṣègbé nípa idà. Ìwọ pa wọ́n run ní ọjọ́ ìbínú rẹ, Ìwọ pa wọ́n láìní àánú. “Bí ó ti ṣe ní ọjọ́ àsè, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe fi ẹ̀rù sí ẹ̀gbẹ́ mi. Ní ọjọ́ ìbínú Olúwa kò sí ẹni tí ó sálà tí ó sì yè; àwọn tí mo ti tọ́jú tí mo sì fẹ́ràn, ni ọ̀tá mi parun.”

Every verse in Lamentations 2

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00