Leviticus 8:6

“Nígbà náà ni Mose mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n.”

Leviticus 8:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 36 in Leviticus chapter 8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Leviticus 8 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Olúwa sọ fún pé, “Mú àti àwọn ọmọ rẹ̀, aṣọ wọn, òróró ìtasórí, akọ màlúù fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀, àgbò méjì àti apẹ̀rẹ̀ tí a kó àkàrà aláìwú sínú rẹ̀. Kí o sì kó gbogbo ìjọ ènìyàn jọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.” Mose sì ṣe bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un, gbogbo ènìyàn sì péjọ sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. Mose sì sọ fún ìjọ ènìyàn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ pé kí á ṣe.” Nígbà náà ni mú àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá síwájú, ó sì fi omi wẹ̀ wọ́n. Ó sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ , ó fi àmùrè dì í, ó wọ̀ ọ́ ní efodu; aṣọ ìgúnwà, ó sì tún wọ̀ ọ́ ni aṣọ ìlekè oyè àlùfáà tí ó ní ìgbànú tí a ṣe ọnà dáradára sí. Ó fi ìgbàyà sí àyà rẹ̀, ó sì fi àti sí ibi ìgbàyà náà. Ó dé e ní fìlà, ó sì fi àwo wúrà tí í ṣe adé mímọ́ síwájú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún . Mose sì fi òróró ìtasórí ya àgọ́ àti ohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ sí mímọ́. Ó wọ́n díẹ̀ nínú òróró yìí sórí pẹpẹ lẹ́ẹ̀méje, ó ta òróró sórí pẹpẹ àti gbogbo ohun èlò àti agbada pẹ̀lú ohun tó gbé agbada yìí dúró láti lè yà á sí mímọ́, ó da díẹ̀ lára òróró ìtasórí yìí sórí , ó sì yà á sí mímọ́. Lẹ́yìn èyí ló mú àwọn ọmọ wá síwájú, ó sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n, ó fi àmùrè dìwọ́n lára, ó fi fìlà dé wọn lórí gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún . Ó sì mú akọ màlúù wá fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀. Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí ẹran náà. Mose pa akọ màlúù náà, ó sì ti ìka bọ inú ẹ̀jẹ̀ náà, ó fi sí orí gbogbo ìwo pẹpẹ láti wẹ pẹpẹ náà mọ́. Ó da ìyókù ẹ̀jẹ̀ náà sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ ní ó ṣe yà á sí mímọ́ láti ṣe ètùtù fún un. Mose tún mú gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn, ó sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ. Ṣùgbọ́n akọ màlúù yìí pẹ̀lú awọ àti ara ẹran àti ìgbẹ́ rẹ̀ ní ó sun lẹ́yìn ibùdó gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti paláṣẹ fún . Lẹ́yìn náà ló mú àgbò wá fún ẹbọ sísun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. Mose sì pa àgbò náà, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. Ó gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, Mose sì sun orí àti àwọn ègé àti ọ̀rá rẹ̀. Ó fi omi fọ gbogbo nǹkan inú àti ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì sun odidi àgbò náà lórí pẹpẹ bí ẹbọ sísun òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa gẹ́gẹ́ bí Olúwa tí pàṣẹ fún . Ó sì mú àgbò kejì wa, èyí ni àgbò ìfinijoyè àlùfáà, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì gbọ́wọ́ lé e lórí. Mose sì pa àgbò náà, ó sì mú díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀, ó tọ́ ọ sí etí ọ̀tún , sórí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún àti ti ẹsẹ̀ ọ̀tún rẹ̀. Mose sì tún mú àwọn ọmọ wá síwájú, ó sì mú ẹ̀jẹ̀ díẹ̀ ó fi sí etí ọ̀tún wọn, àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, ó sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ yí pẹpẹ náà ká. Ó mú ọ̀rá ẹran náà, ìrù rẹ̀ tí ó lọ́ràá, gbogbo ọ̀rá tó wà lára nǹkan inú àti èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀, kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá wọn pẹ̀lú itan ọ̀tún. Lẹ́yìn náà ló mú àkàrà aláìwú sí, èyí tó wà níwájú Olúwa àti àkàrà tí a fi òróró ṣe, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, ó sì kó gbogbo rẹ̀ sórí ọ̀rá àti itan ọ̀tún ẹran náà. Ó kó gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí lé àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, wọ́n sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa. Lẹ́yìn náà, Mose gba gbogbo rẹ̀ lọ́wọ́ wọn, ó sì sun wọn lórí ẹbọ sísun tó wà lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìfinijoyè àlùfáà òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa. Mose sì mú igẹ̀ ẹran náà, èyí tó jẹ́ ìpín rẹ̀ nínú àgbò fún ìfinijoyè, ó sì fì í níwájú Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì, bi Olúwa ti pàṣẹ fún . Mose sì mú díẹ̀ lára òróró ìtasórí àti díẹ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ láti orí pẹpẹ, ó wọ́n sára àwọn ọmọ àti aṣọ rẹ̀, ó sì tún wọ́n sára àwọn ọmọ àti aṣọ wọn. Bẹ́ẹ̀ ní ya àti àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú aṣọ wọn sí mímọ́. Mose sì sọ fún àti àwọn ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ se ẹran náà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé kí ẹ sì jẹ ẹ́ níbẹ̀ pẹ̀lú àkàrà tí a mú láti inú apẹ̀rẹ̀ ọrẹ ìfinijoyè àlùfáà gẹ́gẹ́ bí mo ti pa á láṣẹ pé, ‘Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ni kí ó jẹ ẹ́.’ Kí ẹ fi iná sun ìyókù àkàrà àti ẹran náà. Ẹ má ṣe kúrò ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé fún ọjọ́ méje, títí tí ọjọ́ ìfinijoyè àlùfáà yín yóò fi pé, nítorí pé ìfinijoyè àlùfáà yín yóò gba ọjọ́ méje gbáko. Ohun tí a ṣe lónìí jẹ́ ohun tí Olúwa ti pàṣẹ láti ṣe ètùtù fún yín. Ẹ gbọdọ̀ wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé lọ́sàn án àti lóru fún ọjọ́ méje kí ẹ sì ṣe ohun tí Olúwa fẹ́, kí ẹ má ba à kú, nítorí ohun tí Olúwa pàṣẹ fún mi ni èyí.” Báyìí ni àti àwọn ọmọ rẹ̀ ṣe ohun gbogbo tí Olúwa pàṣẹ láti ẹnu .

Every verse in Leviticus 8

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00