Luke 2:14

““Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.””

Luke 2:14 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 14 of 52 in Luke chapter 2 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Luke 2 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ó sì ṣe ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, àṣẹ ti ọ̀dọ̀ jáde wá pé, kí a kọ orúkọ gbogbo ayé sínú ìwé. (Èyí ni ìkọ sínú ìwé èkínní tí a ṣe nígbà tí fi jẹ baálẹ̀ .) Gbogbo àwọn ènìyàn sì lọ láti kọ orúkọ wọn sínú ìwé, olúkúlùkù sí ìlú ara rẹ̀. Josẹfu pẹ̀lú sì gòkè láti ni , sí ìlú ní , tí à ń pè ní Bẹtilẹhẹmu; nítorí ti ìran àti ìdílé ní í ṣe, láti kọ orúkọ rẹ̀, pẹ̀lú aya rẹ̀ àfẹ́sọ́nà, tí oyún rẹ̀ ti tó bí. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, ọjọ́ rẹ̀ pé tí òun yóò bí. Ó sì bí àkọ́bí rẹ̀ ọmọkùnrin, ó sì fi ọ̀já wé e, ó sì tẹ́ ẹ sínú ibùjẹ ẹran; nítorí tí ààyè kò sí fún wọn nínú ilé èrò. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn ń bẹ tí wọ́n ń gbé ní ìlú náà, wọ́n ń ṣọ́ agbo àgùntàn wọn ní òru ní pápá tí wọ́n ń gbé. Angẹli Olúwa sì yọ sí wọn, ògo Olúwa sì ràn yí wọn ká, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Angẹli náà sì wí fún wọn pé, “Má bẹ̀rù: sá wò ó, mo mú ìyìnrere ayọ̀ ńlá fún yín wá, tí yóò ṣe ti ènìyàn gbogbo. Nítorí a ti bí Olùgbàlà fún yín lónìí ní ìlú , tí í ṣe Olúwa. Èyí ni yóò sì ṣe àmì fún yín; ẹ̀yin yóò rí ọmọ ọwọ́ tí a fi ọ̀já wé, ó dùbúlẹ̀ ní ibùjẹ ẹran.” Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun ọ̀run sì darapọ̀ mọ́ angẹli náà ní òjijì, wọ́n ń yin Ọlọ́run, wí pé, “Ògo ni fún Ọlọ́run lókè ọ̀run, àti ní ayé àlàáfíà, ìfẹ́ inú rere sí ènìyàn.” Ó sì ṣe, nígbà tí àwọn angẹli náà padà kúrò lọ́dọ̀ wọn lọ sí ọ̀run, àwọn olùṣọ́-àgùntàn náà bá ara wọn sọ pé, “Ẹ jẹ́ kí á lọ tààrà sí Bẹtilẹhẹmu, kí á lè rí ohun tí ó ṣẹ̀, tí Olúwa fihàn fún wa.” Wọ́n sì wá lọ́gán, wọ́n sì rí àti ẹfu, àti ọmọ ọwọ́ náà, ó dùbúlẹ̀ nínú ibùjẹ ẹran. Nígbà tí wọ́n sì ti rí i, wọ́n sọ ohun tí a ti wí fún wọn nípa ti ọmọ yìí. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ sí nǹkan wọ̀nyí tí a ti wí fún wọn láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́-àgùntàn wá. Ṣùgbọ́n pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́, ó ń rò wọ́n nínú ọkàn rẹ̀. Àwọn olùṣọ́-àgùntàn sì padà lọ, wọ́n ń fi ògo fún Ọlọ́run, wọ́n sì yìn ín, nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọ́n ti rí, bí a ti wí i fún wọn. Nígbà tí ọjọ́ mẹ́jọ sì pé láti kọ ọmọ náà nílà, wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní , bí a ti sọ ọ́ tẹ́lẹ̀ láti ọ̀dọ̀ angẹli náà wá kí á tó lóyún rẹ̀. Nígbà tí ọjọ́ ìwẹ̀nù sì pé gẹ́gẹ́ bí òfin , Josẹfu àti gbé wá sí ẹmu láti fi í fún Olúwa (bí a ti kọ ọ́ sínú òfin Olúwa pé, “Gbogbo ọmọ ọkùnrin tí ó ṣe àkọ́bí, òun ni a ó pè ní mímọ́ fún Olúwa”), àti láti rú ẹbọ gẹ́gẹ́ bí èyí tí a wí nínú òfin Olúwa: “Àdàbà méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì.” Sì kíyèsi i, ọkùnrin kan wà ní ẹmu, orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ ; ọkùnrin náà sì ṣe olóòtítọ́ àti olùfọkànsìn, ó ń retí ìtùnú ẹli, Ẹ̀mí mímọ́ sì bà lé e. A sì ti fihàn án láti ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ náà wá pé, òun kì yóò rí ikú, kí ó tó rí Olúwa. Ó sì ti ipa Ẹ̀mí wá sínú tẹmpili. Nígbà tí àwọn òbí rẹ̀ sì gbé wá, láti ṣe fún un bí ìṣe òfin. Nígbà náà ni gbé e ní apá rẹ̀, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó ní: “Olúwa Olódùmarè, nígbà yìí ni ó tó jọ̀wọ́ ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ lọ́wọ́ lọ, ní àlàáfíà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ. Nítorí tí ojú mi ti rí ìgbàlà rẹ ná, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀ níwájú ènìyàn gbogbo; ìmọ́lẹ̀ láti mọ́ sí àwọn aláìkọlà, àti ògo ẹli ènìyàn rẹ̀.” Ẹnu sì ya ẹfu àti ìyá rẹ̀ sí nǹkan tí a ń sọ sí i wọ̀nyí. Simeoni sì súre fún wọn, ó sì wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Kíyèsi i, a gbé ọmọ yìí kalẹ̀ fún ìṣubú àti ìdìde ọ̀pọ̀ ènìyàn ní ẹli; àti fún àmì tí a ń sọ̀rọ̀-òdì sí; (idà yóò sì gún ìwọ náà ní ọkàn pẹ̀lú) kí á lè fi ìrònú ọ̀pọ̀ ọkàn hàn.” Ẹnìkan sì ń bẹ, wòlíì, ọmọbìnrin , nínú ẹ̀yà Aṣeri: ọjọ́ ogbó rẹ̀ pọ̀, ó ti bá ọkọ gbé ní ọdún méje láti ìgbà wúńdíá rẹ̀ wá; Ó sì ṣe opó títí ó fi di ẹni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin, ẹni tí kò kúrò ní tẹmpili, ṣùgbọ́n ó ń fi àwẹ̀ àti àdúrà sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru. Ó sì wólẹ̀ ní àkókò náà, ó sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pẹ̀lú, ó sì sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún gbogbo àwọn tí ó ń retí ìdáǹdè ẹmu. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣe nǹkan gbogbo tán gẹ́gẹ́ bí òfin Olúwa, wọ́n padà lọ sí , sí ìlú wọn. Ọmọ náà sì ń dàgbà, ó sì ń lágbára, ó sì kún fún ọgbọ́n: oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run sì ń bẹ lára rẹ̀. Àwọn òbí rẹ̀ a sì máa lọ sí ẹmu ní ọdọọdún sí àjọ ìrékọjá. Nígbà tí ó sì di ọmọ ọdún méjìlá, wọ́n gòkè lọ sí ẹmu gẹ́gẹ́ bí ìṣe àjọ náà. Nígbà tí ọjọ́ wọn sì pé bí wọ́n ti ń padà bọ̀, ọmọ náà, Jesu dúró lẹ́yìn ní ẹmu; Josẹfu àti ìyá rẹ̀ kò mọ̀. Ṣùgbọ́n wọ́n ṣe bí ó wà ní ẹ̀gbẹ́ èrò, wọ́n rin ìrìn ọjọ́ kan; wọ́n wá a kiri nínú àwọn ará àti àwọn ojúlùmọ̀ wọn. Nígbà tí wọn kò sì rí i, wọ́n padà sí ẹmu, wọ́n ń wá a kiri. Ó sì ṣe, lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta wọ́n rí i nínú tẹmpili ó jókòó ní àárín àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ tiwọn, ó sì ń bi wọ́n léèrè. Ẹnu sì ya gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún òye àti ìdáhùn rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì rí i, háà ṣe wọ́n, ìyá rẹ̀ sì bi í pé, “Ọmọ, èéṣe tí ìwọ fi ṣe wá bẹ́ẹ̀? Sá wò ó, baba rẹ̀ àti èmi ti ń fi ìbànújẹ́ wá ọ kiri.” Ó sì dáhùn wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ẹ̀yin fi ń wá mi kiri? Ẹ̀yin kò mọ̀ pé èmi kò lè ṣàìmá wà níbi iṣẹ́ mi?” Ọ̀rọ̀ tí o sọ kò sì yé wọn. Ó sì bá wọn sọ̀kalẹ̀ lọ sí , sì fi ara balẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ pa gbogbo nǹkan wọ̀nyí mọ́ nínú ọkàn rẹ̀. Jesu sì ń pọ̀ ní ọgbọ́n, sì ń dàgbà, ó sì wà ní ojúrere ní ọ̀dọ̀ Ọlọ́run àti ènìyàn.

Every verse in Luke 2

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00