Luke 4:6

“Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún.”

Luke 4:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 44 in Luke chapter 4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Luke 4 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Jesu sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó padà ti wá, a sì ti ọwọ́ Ẹ̀mí darí rẹ̀ sí ijù, Ogójì ọjọ́ ni a fi dán an wò lọ́wọ́ èṣù. Kò sì jẹ ohunkóhun ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì: nígbà tí wọ́n sì parí, lẹ́yìn náà ni ebi wá ń pa á. Èṣù sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ fún òkúta yìí kí ó di àkàrà.” Jesu sì dáhùn, ó wí fún un pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ènìyàn kì yóò wà láààyè nípa àkàrà nìkan.’ ” Lójúkan náà, èṣù sì mú un lọ sí orí òkè gíga, ó sì fi gbogbo ilẹ̀ ọba ayé hàn án. Èṣù sì wí fún un pé, “Ìwọ ni èmi ó fi gbogbo agbára yìí àti ògo wọn fún: nítorí á sá ti fi fún mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù mí, èmi a fi í fún. Ǹjẹ́ bí ìwọ bá foríbalẹ̀ fún mi, gbogbo rẹ̀ ni yóò jẹ́ tìrẹ.” Jesu sì dáhùn ó sì wí fún un pé, “Kúrò lẹ́yìn mi, Satani, nítorí tí a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ìwọ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, òun nìkan ṣoṣo ni kí ìwọ kí ó sì máa sìn.’ ” Èṣù sì mú un lọ sí ẹmu, ó sì gbé e lé ibi ṣóńṣó tẹmpili, ó sì wí fún un pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ láti ibí yìí. A sá ti kọ̀wé rẹ̀ pé, “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣe ìtọ́jú rẹ; àti pé ní ọwọ́ wọn ni wọn ó gbé ọ sókè, kí ìwọ kí ó má ba à fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ” Jesu sì dáhùn ó wí fún un pé, “A ti kọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ dán Olúwa Ọlọ́run rẹ wò.’ ” Nígbà tí èṣù sì parí ìdánwò náà gbogbo, ó fi í sílẹ̀ lọ fun sá à kan. Jesu sì fi agbára Ẹ̀mí padà wá sí , òkìkí rẹ̀ sì kàn kálẹ̀ ní gbogbo agbègbè tí ó yí i ká. Ó sì ń kọ́ni nínú ọgu wọn; a ń yìn ín lógo láti ọ̀dọ̀ gbogbo àwọn ènìyàn wá. Ó sì wá sí , níbi tí a gbé ti tọ́ ọ dàgbà: bí ìṣe rẹ̀ ti rí, ó sì wọ inú ọgu lọ ní ọjọ́ ìsinmi, ó sì dìde láti kàwé. A sì fi ìwé wòlíì fún un. Nígbà tí ó sì ṣí ìwé náà, ó rí ibi tí a gbé kọ ọ́ pé: “Ẹ̀mí Olúwa ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fi àmì òróró yàn mí láti wàásù ìyìnrere fún àwọn òtòṣì. Ó ti rán mi wá láti wàásù ìdásílẹ̀ fún àwọn ìgbèkùn, àti ìmúnríran fún àwọn afọ́jú, àti láti jọ̀wọ́ àwọn tí a pa lára lọ́wọ́, láti kéde ọdún ojúrere Olúwa.” Ó sì pa ìwé náà dé, ó fi í fún ìránṣẹ́, ó sì jókòó. Gbogbo àwọn tí ó ń bẹ nínú ọgu sì tẹjúmọ́ ọn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wí fún wọn pé, “Lónìí ìwé mímọ́ yìí ṣẹ ní etí yín.” Gbogbo wọn sì jẹ́rìí rẹ̀, háà sì ṣe wọ́n sí ọ̀rọ̀ oore-ọ̀fẹ́ tí ń jáde ní ẹnu rẹ̀, wọ́n sì wí pé, “Ọmọ ẹfu kọ́ yìí?” Jesu sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni ẹ̀yin ó pa òwe yìí sí mi pé, ‘íṣègùn, wo ara rẹ̀ sàn! Àwọn ohun tí àwa gbọ́ pé o ti ọwọ́ rẹ ṣe ní , ṣe é níhìn-ín yìí pẹ̀lú ní ilẹ̀ ara rẹ.’ ” Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó púpọ̀ ni ó wà ní ẹli nígbà ọjọ́ wòlíì , nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo. Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní , ìlú kan ní . Adẹ́tẹ̀ púpọ̀ ní sì ń bẹ ní ẹli nígbà wòlíì ṣa; kò sì ṣí ọ̀kan nínú wọn tí a wẹ̀nùmọ́, bí kò ṣe ará .” Nígbà tí gbogbo àwọn tí ó wà nínú ọgu gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, inú bi wọ́n gidigidi, wọ́n sì dìde, wọ́n tì í sóde sí ẹ̀yìn ìlú, wọ́n sì fà á lọ sí bèbè òkè níbi tí wọ́n gbé tẹ ìlú wọn dó, kí wọn bá à lè sọ sílẹ̀ ní ògèdèǹgbé. Ṣùgbọ́n ó kọjá láàrín wọn, ó bá tirẹ̀ lọ. Ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí , ìlú kan ní , ó sì ń kọ́ wọn ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹnu sì yà wọ́n sí ẹ̀kọ́ rẹ̀: nítorí tàṣẹtàṣẹ ni ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin kan sì wà nínú ọgu, ẹni tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́, ó kígbe ní ohùn rara, “Ó wí pé, kín ni ṣe tàwa tìrẹ, Jesu ará ? Ìwọ́ wá láti pa wá run bí? Èmí mọ ẹni tí ìwọ í ṣe, Ẹni Mímọ́ Ọlọ́run.” Jesu sì bá a wí gidigidi, ó wí fun pe, “Pa ẹnu rẹ mọ́, kí o sì jáde lára rẹ̀.” Nígbà tí ẹ̀mí èṣù náà sì gbé e ṣánlẹ̀ ní àwùjọ, ó jáde kúrò lára rẹ̀, kò sì pa á lára. Ẹnu sì ya gbogbo wọn, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ wí pé, “Irú ẹ̀kọ́ kín ni èyí? Nítorí pẹ̀lú àṣẹ àti agbára ni ó fi bá àwọn ẹ̀mí àìmọ́ wí, wọ́n sì jáde kúrò.” Òkìkí rẹ̀ sì kàn níbi gbogbo ní agbègbè ilẹ̀ náà yíká. Nígbà tí ó sì dìde kúrò nínú ọgu, ó sì wọ̀ ilé lọ; ibà sì ti dá ìyá ìyàwó dùbúlẹ̀, wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ nítorí rẹ̀. Ó sì súnmọ́ ọ, ó bá ibà náà wí; ibà sì náà sì fi sílẹ̀. O sì dìde lọ́gán, ó ń ṣe ìránṣẹ́ fún wọn. Nígbà tí oòrùn sì ń wọ̀, àwọn ènìyàn gbe àwọn aláìsàn, tó ní írúú àìsàn wá sọ́dọ̀ ; ó sì fi ọwọ́ lé olúkúlùkù wọn, ó sì mú wọn láradá. Àwọn ẹ̀mí èṣù sì jáde lára ẹni púpọ̀ pẹ̀lú, wọ́n ń kígbe, wí pé, “Ìwọ ni Ọmọ Ọlọ́run!” Ó sì ń bá wọn wí kò sì jẹ́ kí wọn kí ó fọhùn, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé Òun ni náà. Nígbà tí ilẹ̀ sì mọ́, Jesu sì jáde lọ, ó sì ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀. Ìjọ ènìyàn sì ń wá a kiri, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá, wọ́n sì dá a dúró, nítorí kí ó má ba à lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn. Ṣùgbọ́n ó sì wí fún wọn pé, “Èmi kò lè ṣàìmá wàásù ìyìnrere ti ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú mìíràn pẹ̀lú, nítorí náà ni a sá ṣe rán mi.” Ó sì ń wàásù nínú ọgu ti .

Every verse in Luke 4

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00