Matthew 17:17

“Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.””

Matthew 17:17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 17 of 27 in Matthew chapter 17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Matthew 17 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́fà, Jesu mú , Jakọbu àti arákùnrin rẹ̀, ó mú wọn lọ sí orí òkè gíga kan tí ó dádúró. Níbẹ̀ ara rẹ̀ yí padà níwájú wọn. Ojú rẹ̀ sì ràn bí oòrùn, aṣọ rẹ̀ sì funfun bí ìmọ́lẹ̀. Lójijì, Mose àti fi ara hàn, wọ́n sì ń bá sọ̀rọ̀. Peteru sọ fún pé, “Olúwa, jẹ́ kí a kúkú máa gbé níhìn-ín yìí. Bí ìwọ bá fẹ́, èmi yóò pa àgọ́ mẹ́ta, ọ̀kan fún ọ, ọ̀kan fún , àti ọ̀kan fún .” Bí ti sọ̀rọ̀ tán, àwọsánmọ̀ dídán síji bò wọ́n, láti inú rẹ̀ ohùn kan wí pé, “Èyí ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni ti inú mi dùn sí gidigidi. Ẹ máa gbọ́ tirẹ̀!” Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ti gbọ́ èyí, wọ́n dojúbolẹ̀. Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi. Ṣùgbọ́n sì tọ̀ wọ́n wá. Ó fi ọwọ́ kàn wọ́n, ó wí pé, “Ẹ dìde, ẹ má ṣe bẹ̀rù.” Nígbà tí wọ́n sì gbé ojú wọn sókè, tí wọ́n sì wò ó, Jesu nìkan ni wọn rí. Bí wọ́n sì ti ń sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, Jesu pàṣẹ fún wọn pé, “Ẹ kò gbọdọ̀ sọ fún ẹnikẹ́ni ohun tí ẹ rí, títí Ọmọ Ènìyàn yóò fi jí dìde kúrò nínú òkú.” Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ́ pé, “Kí ni ó fà á tí àwọn olùkọ́ òfin fi ń wí pé, ní láti kọ́ padà wá?” Jesu sì dáhùn pé, “Dájúdájú òtítọ́ ni wọ́n ń sọ. wá láti fi gbogbo nǹkan sí ipò. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín lóòótọ́; ti dé. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ ọ́n, ọ̀pọ̀ tilẹ̀ hu ìwà búburú sí i. Bákan náà, Ọmọ Ènìyàn náà yóò jìyà lọ́wọ́ wọn pẹ̀lú.” Nígbà náà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mọ̀ pé ó n sọ̀rọ̀ nípa ítẹ̀bọmi fún wọn ni. Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ ìjọ ènìyàn, ọkùnrin kan tọ̀ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, ṣàánú fún ọmọ mi, nítorí tí ó ní wárápá. Ó sì ń joró gidigidi, nígbà púpọ̀ ni ó máa ń ṣubú sínú iná tàbí sínú omi. Mo sì ti mú un tọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ, ṣùgbọ́n wọn kò lè wò ó sàn.” Jesu sì dáhùn wí pé, “A! Ẹ̀yìn alágídí ọkàn àti aláìgbàgbọ́ ènìyàn, èmi yóò ti bá yín gbé pẹ́ tó? Èmi ó sì ti fi ara dà á fún yín tó? Ẹ mú un wá sọ́dọ̀ mi níhìn-ín yìí.” Nígbà náà ni bá ẹ̀mí èṣù tí ó ń bẹ nínú ọmọkùnrin náà wí, ó sì fi í sílẹ̀, à mú ọmọkùnrin náà láradá láti ìgbà náà lọ. Lẹ́yìn èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi níkọ̀kọ̀ pé, “Èéṣe tí àwa kò lè lé ẹ̀mí èṣù náà jáde?” Jesu sọ fún wọn pé, “Nítorí ìgbàgbọ́ yín kéré. Lóòótọ́ ni mo wí fún yin, bí ẹ bá ni ìgbàgbọ́, bí ó tilẹ̀ kéré bí hóró musitadi, ẹ̀yin lè wí fún òkè yìí pé, ‘Sípò kúrò níhìn-ín yìí,’ òun yóò sì ṣí ipò. Kò sì ní sí ohun tí kò ní í ṣe é ṣe fún yín.” Nígbà tí wọ́n sì ti wà ní , Jesu sọ fún wọn pé, “Láìpẹ́ yìí a ó fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́. Wọn yóò sì pa á, ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn èyí, yóò sì jí dìde sí ìyè.” Ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi. Nígbà tí àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì dé , àwọn agbowó òde tí ń gba owó idẹ méjì tó jẹ́ owó tẹmpili tọ wá wọ́n sì bí i pé, “Ǹjẹ́ olùkọ́ yín ń san owó tẹmpili?” Peteru sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń san.” Nígbà tí wọ ilé láti bá sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Jesu ni ó kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, Jesu bí i pé, “Kí ni ìwọ rò, Simoni? Ǹjẹ́ àwọn ọba ayé ń gba owó orí lọ́wọ́ àwọn ọmọ wọn tàbí lọ́wọ́ àwọn àlejò?” Peteru dáhùn pé, “Lọ́wọ́ àwọn àlejò ni.” sì tún wí pé, “Èyí jẹ́ wí pé àwọn ọmọ ílẹ̀ kì í san owó òde? Síbẹ̀síbẹ̀, àwa kò fẹ́ mú wọn bínú. Nítorí náà, ẹ lọ sí etí Òkun, kí ẹ sì sọ ìwọ̀ sí omi. Ẹ mú ẹja àkọ́kọ́ tí ẹ kọ́ fà sókè, ẹ ya ẹnu rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì rí owó idẹ kan níbẹ̀, ki ẹ fi fún wọn fún owó orí tèmi àti tirẹ̀.”

Every verse in Matthew 17

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00