Matthew 3:11
““Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín.”
Matthew 3:11 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 11 of 17 in Matthew chapter 3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
1 thread runs through this chapter
Matthew 3 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ní ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, Johanu ítẹ̀bọmi wá, ó ń wàásù ní aginjù . Ó ń wí pé, “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.” Èyí ni ẹni náà ti wòlíì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ pé, “Ohùn ẹni ti ń kígbe ní ijù, ‘Ẹ tún ọ̀nà Olúwa ṣe, ẹ ṣe ojú ọ̀nà rẹ̀ kí ó tọ́.’ ” Aṣọ náà sì jẹ́ ti irun ìbákasẹ, ó sì di àmùrè awọ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Eṣú àti oyin ìgàn sì ni oúnjẹ rẹ̀. Àwọn ènìyàn jáde lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ láti ẹmu àti gbogbo àti àwọn ènìyàn láti gbogbo ìhà . Wọ́n ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn, a sì ń bamitiisi wọn ní ọ̀dọ̀ rẹ̀ ní odò . Ṣùgbọ́n nígbà tí ó rí ọ̀pọ̀ àwọn àti tí wọ́n ń wá ṣe ìtẹ̀bọmi, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọ paramọ́lẹ̀! Ta ni ó kìlọ̀ fún yín pé kí ẹ́ sá kúrò nínú ìbínú tí ń bọ̀? Ẹ so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà. Kí ẹ má sì ṣe rò nínú ara yin pé, ‘Àwa ní ní baba.’ Èmi wí fún yín, Ọlọ́run lè mu àwọn ọmọ jáde láti inú àwọn òkúta wọ̀nyí wá fún . Nísinsin yìí, a ti fi àáké lè gbòǹgbò igi, àti pé gbogbo igi tí kò bá so èso rere ni a óò ge lulẹ̀ ti a ó sì wọ jù sínú iná. “Èmi fi omi bamitiisi yín fún ìrònúpìwàdà. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn mi ẹnìkan tí ó pọ̀jù mí lọ ń bọ̀, bàtà ẹni tí èmi kò tó gbé. Òun ni yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ àti iná bamitiisi yín. Ẹni ti àmúga ìpakà rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ̀, yóò gbá ilẹ̀ ìpakà rẹ̀, yóò kó alikama rẹ̀ sínú àká, ṣùgbọ́n ìyàngbò ni yóò fi iná àjóòkú sun.” Nígbà náà ni ti wá sí odò kí bá à lè ṣe ìtẹ̀bọmi fún un. Ṣùgbọ́n kò fẹ́ ṣe ìtẹ̀bọmi fún un, ó wí pé, “Ìwọ ni ìbá bamitiisi fún mi, ìwọ sì tọ̀ mí wá?” Jesu sì dáhùn pé, “Jọ̀wọ́ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ náà, nítorí bẹ́ẹ̀ ni ó yẹ fún wa láti mú gbogbo òdodo ṣẹ.” Bẹ́ẹ̀ ni gbà, ó sì ṣe ìtẹ̀bọmi fún un. Bí ó si tí ṣe ìtẹ̀bọmi fún tán, Ó jáde láti inú omi. Ní àkókò náà ọ̀run ṣí sílẹ̀ fún un, Ó sì rí Ẹ̀mí Ọlọ́run ń sọ̀kalẹ̀ bí àdàbà, ó sì bà lé e. Ohùn kan láti ọ̀run wá sì wí pé, “Èyí sì ni àyànfẹ́ ọmọ mi, ẹni tí inú mi dùn sí gidigidi.”
Every verse in Matthew 3
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.