Nehemiah 7:37
“Lodi, Hadidi, àti Ono jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan (721)”
Nehemiah 7:37 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 37 of 73 in Nehemiah chapter 7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Nehemiah 7 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Lẹ́yìn ìgbà tí a tún odi mọ tán tí mo sì ri àwọn ìlẹ̀kùn sí ààyè wọn, a sì yan àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin àti àwọn . Mo fún arákùnrin mi pẹ̀lú olórí ilé ìṣọ́ ní àṣẹ lórí ẹmu, nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn olóòtítọ́, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run jù bí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ti ṣe lọ. Mo sọ fún wọn pé, “A kò gbọdọ̀ ṣí ìlẹ̀kùn ẹmu títí oòrùn yóò fi mú. Nígbà tí àwọn aṣọ́bodè bá sì wà lẹ́nu iṣẹ́, jẹ́ kí wọn ti ìlẹ̀kùn kí wọn sì há wọn. Bákan náà, yàn nínú àwọn tí ń gbé ẹmu gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́. Àwọn mìíràn níbi tí a pín wọn sí àti àwọn mìíràn ní tòsí ilé e wọn.” Ìlú náà tóbi ó sì ní ààyè, ṣùgbọ́n ènìyàn inú rẹ̀ kéré, a kò sì tí ì tún àwọn ilé inú rẹ̀ kọ́. Nígbà náà ni Ọlọ́run mi fi sí mi ní ọkàn láti kó àwọn ọlọ́lá, àwọn ìjòyè, àti àwọn ènìyàn jọ fún ìforúkọsílẹ̀ ní ìdílé ìdílé. Mo rí ìwé àkọsílẹ̀ ìtàn ìran àwọn tí ó kọ́ gòkè padà wá láti ìgbèkùn. Èyí ni ohun tí mo rí tí a kọ sínú ìwé náà. Èyí ni àwọn ènìyàn agbègbè náà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti ìgbèkùn, àwọn tí ọba ti kó ní ìgbèkùn (wọ́n padà sí ẹmu àti , olúkúlùkù sí ìlú u rẹ̀. Wọ́n jọ rìn wá pẹ̀lú u , Jeṣua, , Asariah, Raamiah, Nahamani, Mordekai, Bilṣani, Misperi, Bigfai, Nehumu, àti ). Àkọsílẹ̀ orúkọ àwọn ọkùnrin ẹli, àwọn ọmọ ṣi jẹ́ ẹgbàá ó lé méjìléláàádọ́sàn-án (2,172) Ṣefatia jẹ́ òjìdínnírinwó ó lé méjìlá (372) Arah jẹ́ ẹgbẹ̀tàléláàádọ́ta ó lé méjì (652) Pahati- (láti ipasẹ̀ ọmọ Jeṣua àti ) jẹ́ ẹgbàá mẹ́rìnlá ó lé méjìdínlógún (2,818) Elamu jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀fà ó lé mẹ́rin (1,254) Sattu jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀rin ó lé márùn-ún (845) Sakkai jẹ́ òjìdínlẹ́gbẹ̀rin (760) Binnui jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́jọ (648) Bebai jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (628) Asgadi jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó dín méjìdínlọ́gọ́rin (2,322) Adonikami jẹ́ ọ̀tàlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méje (667) Bigfai jẹ́ ẹgbàá ó lé mẹ́tàdínláàádọ́rin (2,067) Adini jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀ta ó lé márùn-ún (655) Ateri (láti ipasẹ̀ ) jẹ́ méjìdínlọ́gọ́rùn-ún (98) Haṣumu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́jọ (328) Besai jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó ó lé mẹ́rin (324) Harifu jẹ́ méjìléláàádọ́fà (112) Gibeoni jẹ́ márùndínlọ́gọ́rùn (95). Àwọn ọmọ Bẹtilẹhẹmu àti jẹ́ igba ó dín méjìlélógún (188) Anatoti jẹ́ méjìdínláàádóje (128) Beti- jẹ́ méjìlélógójì (42) Kiriati-, Kefira, àti jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó lé mẹ́ta (743) Rama àti jẹ́ ẹgbẹ̀ta ó lé mọ́kànlélógún (621) Mikmasi jẹ́ méjìlélọ́gọ́fà (122) Beteli àti jẹ́ mẹ́tàlélọ́gọ́fà (123) Nebo mìíràn jẹ́ méjìléláàádọ́ta (52) Elamu mìíràn jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́rìnléláàádọ́ta (1,254) Harimu jẹ́ ọ̀rìndínnírinwó (320) Jeriko jẹ́ ọ̀tàdínnírinwó ó lé márùn-ún (345). Lodi, Hadidi, àti jẹ́ ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀rin ó lé ọ̀kan (721) Senaa jẹ́ ẹgbàajì ó dín àádọ́rin (3,930). Àwọn àlùfáà: àwọn ọmọ (láti ipasẹ̀ ìdílé Jeṣua) jẹ́ ogún dín lẹ́gbẹ̀rin ó dín méje (973) Immeri jẹ́ àádọ́ta lé lẹ́gbẹ̀rún ó lé méjì (1,052) Paṣuri jẹ́ ẹgbẹ̀fà ó lé mẹ́tàdínláàádọ́ta (1,247) Harimu jẹ́ ẹgbẹ̀rún ó lé mẹ́tàdínlógún (1,017). Àwọn ọmọ : àwọn ọmọ Jeṣua (láti ipasẹ̀ , láti ipasẹ̀ ) jẹ́ mẹ́rìnléláàádọ́rin (74). Àwọn akọrin: àwọn ọmọ jẹ́ méjìdínláàádọ́jọ (148). Àwọn aṣọ́nà: àwọn ọmọ Ṣallumu, Ateri, Talmoni, Akkubu, Hatita, àti Ṣobai jẹ́ méjìdínlógóje (138). Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili. Àwọn ọmọ , Hasufa, Tabboati, Kerosi, Sia, Padoni, Lebana, Hagaba, Ṣalmai, Hanani, Giddeli, Gahari, Reaiah, Resini, Nekoda, Gassamu, Ussa, Pasea, Besai, Mehuni, Nefisimu, Bakbu, Hakufa, Harhuri, Basluti, Mehida, Harṣa, Barkosi, , Tema, Nesia, àti . Àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ : àwọn ọmọ , Sofereti; Perida, Jaala, Darkoni, Giddeli, Ṣefatia, Hattili, Pokereti-Haṣṣebaimu, àti . Àwọn ìránṣẹ́ tẹmpili àti àwọn ọmọ ìránṣẹ́ jẹ́ irinwó ó dín mẹ́jọ (392). Àwọn wọ̀nyí gòkè wá láti àwọn ìlú ti -, Teli-ṣa, Kerubu, Addoni àti , ṣùgbọ́n wọn kò lè sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé ìdílé àwọn wá láti ara ìran ẹ̀yà ẹli. Àwọn ọmọ , àti jẹ́ òjìlélẹ́gbẹ̀ta ó lé méjì (642). Lára àwọn àlùfáà ni: àwọn ọmọ , Hakosi àti (ọkùnrin tí ó fẹ́ ọmọbìnrin ará , ẹni tí a ń fi orúkọ yìí pè). Àwọn wọ̀nyí wá àkọsílẹ̀ orúkọ ìran wọn, ṣùgbọ́n wọn kò rí í níbẹ̀, fún ìdí èyí, a yọ wọ́n kúrò nínú àwọn tí ń ṣiṣẹ́ àlùfáà gẹ́gẹ́ bí aláìmọ́. Baálẹ̀ sọ fún wọn nítorí náà pé wọn kò gbọdọ̀ kópa nínú jíjẹ oúnjẹ mímọ́ títí tí àlùfáà tí yóò wá tí ń ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú àti yóò fi dé. Gbogbo ìjọ ènìyàn náà jẹ́ ẹgbàá mọ́kànlélógún ó lé òjìdínnírinwó (42,360), yàtọ̀ sí àwọn ìránṣẹ́kùnrin àti ìránṣẹ́bìnrin tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀ta dín lẹ́gbàárin ó dín ẹ̀tàlélọ́gọ́ta (7,337); wọ́n sì tún ní àwọn akọrin ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ òjìlúgba ó lé márùn-ún (245). Ẹṣin wọn jẹ́ ọ̀tàdínlẹ́gbẹ̀rin ó dín mẹ́rin (736), ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlúgba ó dín márùn-ún (245); ìbákasẹ wọn jẹ́ òjìlénírinwó ó dín márùn-ún (435); kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rìnlélọ́gbọ̀n ó dín ọgọ́rin (6,720). Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé náà kópa nínú ṣíṣe iṣẹ́ náà. Baálẹ̀ fún ilé ìṣúra ní ẹgbẹ̀rún (1,000) dariki wúrà, àádọ́ta àwo koto àti ọ̀rìndínlẹ́gbẹ̀ta lé mẹ́wàá (530) ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. Díẹ̀ lára àwọn olórí ìdílé fún ilé ìṣúra ní ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà àti ẹgbọ̀kànlá (2,200) fàdákà. Àròpọ̀ gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn tókù fi sílẹ̀ jẹ́ ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) dariki wúrà, ẹgbẹ̀rún méjì (2,000) fàdákà àti ẹẹ́tàdínláàdọ́rin ẹ̀wù fún àwọn àlùfáà. Àwọn àlùfáà, àwọn , àwọn aṣọ́bodè, àwọn akọrin, àwọn ènìyàn díẹ̀, àwọn ìránṣẹ́ ilé Ọlọ́run, àti gbogbo ènìyàn ẹli wà ní ìlú wọn. Nígbà tí ó di oṣù keje, tí àwọn ọmọ ẹli sì ti wà nínú ìlú u wọn,
Every verse in Nehemiah 7
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.