Numbers 10:3
“Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé.”
Numbers 10:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 36 in Numbers chapter 10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Numbers 10 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Olúwa sọ fún pé, “Ṣe fèrè fàdákà méjì pẹ̀lú fàdákà lílù, kí o máa lò ó láti máa fi pe ìjọ ènìyàn àti láti máa fi darí ìrìnàjò lọ sí ibùdó yín. Nígbà tí o bá fọn méjèèjì gbogbo ìjọ ènìyàn yóò pé síwájú rẹ ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ ìpàdé. Bí ó bá jẹ́ ọ̀kan ni o fọn, nígbà náà ni àwọn olórí ẹ̀yà ẹli yóò péjọ síwájú rẹ. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì, àwọn ẹ̀yà tó pa ibùdó sí ìhà ìlà-oòrùn ni yóò gbéra. Nígbà tí o bá fun ìpè ìdágìrì kejì, ibùdó tó wà ní ìhà gúúsù ni yóò gbéra. Ìpè ìdágìrì yìí ni yóò jẹ́ àmì fún gbígbéra. Nígbà tí o bá fẹ́ pe ìjọ ènìyàn jọ, fun fèrè nìkan, má ṣe fun ti ìdágìrì pẹ̀lú rẹ̀. “Àwọn ọmọ tí í ṣe àlùfáà ni kí ó máa fun fèrè. Èyí yóò jẹ́ ìlànà láéláé fún yín àti fún ìran tó ń bọ̀. Nígbà tí ẹ bá lọ jagun pẹ̀lú àwọn ọ̀tá tó ń ni yín lára ní ilẹ̀ yín, ẹ fun ìpè ìdágìrì pẹ̀lú fèrè. A ó sì rántí yín níwájú Olúwa, Ọlọ́run yín yóò sì gbà yín lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni ní ọjọ́ ayọ̀ yín, ní gbogbo àjọ̀dún tí a yàn àti ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yín, ni kí ẹ máa fun fèrè lórí ẹbọ sísun àti ọrẹ àlàáfíà yín, wọn yóò sì jẹ́ ìrántí fún yín níwájú Ọlọ́run. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín.” Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùùkuu kúrò lórí tabanaku ẹ̀rí. Àwọn ọmọ ẹli sì gbéra kúrò ní aginjù wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùùkuu fi dúró sí aginjù . Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu . Àwọn ìpín ti ibùdó ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn ṣoni ọmọ ni ọ̀gágun wọn. Netaneli ọmọ ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà ; Eliabu ọmọ ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà . Nígbà náà ni wọ́n sọ tabanaku kalẹ̀ àwọn ọmọ ṣoni àti tó gbé àgọ́ sì gbéra. Àwọn ìpín ti ibùdó ti ló gbéra tẹ̀lé wọn, lábẹ́ ọ̀págun wọn. Elisuri ọmọ Ṣedeuri ni ọ̀gágun wọn. Ṣelumieli ọmọ ṣaddai ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà . Eliasafu ọmọ ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà . Nígbà náà ni àwọn ọmọ tí ń ru ohun mímọ́ náà gbéra. Àwọn ti àkọ́kọ́ yóò sì ti gbé tabanaku dúró kí wọn tó dé. Àwọn ìpín tó wà ní ibùdó ló tún kàn lábẹ́ ọ̀págun wọn. ṣama ọmọ ni ọ̀gágun wọn. Gamalieli ọmọ ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà . Abidani ọmọ ni ọ̀gágun ìpín ti ẹ̀yà . Lákòótan, àwọn ọmọ-ogun tó ń mójútó ẹ̀yìn ló tún kàn, àwọn ni ìpín ti ibùdó lábẹ́ ọ̀págun wọn. Ahieseri ọmọ ṣaddai ni ọ̀gágun wọn. Pagieli ọmọ ni ìpín ti ẹ̀yà Aṣeri, Ahira ọmọ ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà . Báyìí ni àwọn ọmọ ẹli ṣe tò jáde gẹ́gẹ́ bí ogun nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wọn. Mose sì sọ fún ọmọ ará tí í ṣe àna rẹ̀ pé, “A ń gbéra láti lọ sí ibi tí Olúwa sọ pé, ‘Èmi ó fi fún un yín.’ Bá wa lọ, àwa ó ṣe ọ́ dáradára nítorí pé Olúwa ti ṣèlérí ohun rere fún ẹli.” Ó sì dáhùn pé, “Rárá, èmi kò ní bá yín lọ, mò ń padà lọ sí ilẹ̀ mi àti sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi.” Mose sì sọ pé, “Jọ̀wọ́ ma fi wá sílẹ̀, ìwọ mọ ibi tí a lè pa ibùdó sí nínú aginjù, ìwọ yóò sì jẹ́ ojú fún wa. Bí o bá bá wa lọ, a ó sì pín fún ọ nínú ohun rere yówù tí Olúwa bá fún wa.” Wọ́n sì gbéra láti orí òkè Olúwa ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Àpótí ẹ̀rí Olúwa ń lọ níwájú wọn fún gbogbo ọjọ́ mẹ́ta yìí láti wá ibi ìsinmi fún wọn. Ìkùùkuu Olúwa wà lórí wọn lọ́sàn nígbà tí wọ́n gbéra kúrò ní ibùdó. Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá gbéra yóò sì wí pé, “Dìde, Olúwa! Kí a tú àwọn ọ̀tá rẹ ká, kí àwọn tí ó kórìíra rẹ sì sálọ níwájú rẹ.” Nígbàkígbà tí àpótí ẹ̀rí bá sinmi yóò wí pé, “Padà, Olúwa, sọ́dọ̀ àwọn àìmoye ẹgbẹẹgbẹ̀rún ẹli.”
Every verse in Numbers 10
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.