Numbers 24:18
“Wọn yóò borí Edomu; yóò ṣẹ́gun Seiri ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n Israẹli yóò dàgbà nínú agbára.”
Numbers 24:18 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 18 of 25 in Numbers chapter 24 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Numbers 24 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Nísinsin yìí nígbà tí rí i wí pé ó tẹ́ Olúwa lọ́rùn láti bùkún àwọn ẹli, kò lo ọ̀nà ìṣoṣó gẹ́gẹ́ bí ti ìgbà ìṣáájú, ṣùgbọ́n ó yí ojú rẹ̀ sí apá aginjù. Nígbà tí wo ìta ó sì rí ẹli tí wọ́n pàgọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà wọn, Ẹ̀mí Ọlọ́run sì bà sórí rẹ̀ ó sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀, “Àsọtẹ́lẹ̀ tí ọmọ , àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, àsọtẹ́lẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dojúbolẹ̀, tí ojú rẹ̀ là kedere. “Àgọ́ rẹ ti dára tó, ìwọ ọbu, àti ibùgbé rẹ, ìwọ ẹli! “Gẹ́gẹ́ bí àfonífojì tí ó tàn jáde, gẹ́gẹ́ bí ọgbà tí ó wà ní ẹ̀bá odò ńlá, gẹ́gẹ́ bí igi aloe tí Olúwa gbìn, gẹ́gẹ́ bí igi kedari tí ó wà lẹ́bàá odò. Omi yóò sàn láti inú garawa: èso wọn yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ omi. “Ọba wọn yóò ga ju lọ; ìjọba wọn yóò di gbígbéga. “Ọlọ́run mú wọn jáde láti wá; wọ́n ní agbára gẹ́gẹ́ bí i ti àgbáǹréré. Wọ́n jẹ orílẹ̀-èdè tí ń ṣe ọ̀tá rẹ̀ run, wọ́n sì fọ́ egungun wọn sí túútúú; wọ́n ó sì fi ọfà wọn ta wọ́n ní àtapòyọ. Ó tẹríba ó sì dùbúlẹ̀ bí kìnnìún, bí abo kìnnìún: ta ni ó gbọdọ̀ jí wọn? “Ìbùkún ni fún ẹni tí ó bùkún fún ọ, kí ìfibú jẹ́ ti ẹni tí ó fi ọ́ bú!” Nígbà náà ni ìbínú sì dé sí . Ó sì fi ọwọ́ lu ọwọ́ ó wí pé, “Mo pè ọ́ láti bú àwọn ọ̀tá mi ṣùgbọ́n o tún bùkún fún wọn nígbà mẹ́ta yìí. Nísinsin yìí sálọ sí ibùjókòó rẹ! Èmi ti rò láti sọ ọ́ di ẹni ńlá, ṣùgbọ́n Olúwa tí fà ọ́ sẹ́yìn láti gba èrè yìí.” Balaamu dá lóhùn, “Ǹjẹ́ èmi kò sọ fún àwọn ìránṣẹ́ tí o rán sí mi wí pé, ‘Kódà bí bá fún mi ní ààfin rẹ̀ tí ó kún fún fàdákà àti wúrà, èmi kò le ṣe ohunkóhun lọ́wọ́ ara mi, yálà búburú tàbí rere, láti kọjá òfin Olúwa: ohun tí Olúwa bá wí ni èmi ó sọ’? Nísinsin yìí mò ń padà lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn mi, ṣùgbọ́n jẹ́ kí èmi kí ó kìlọ̀ fún ọ nítorí nǹkan tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ ní ọjọ́ iwájú.” Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe: “Òwe ọmọ , òwe ẹni tí ojú rẹ̀ ríran kedere, ẹni tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń wí, tí ó sì mọ ìmọ̀ Ọ̀gá-ògo, tí ó ríran láti ọ̀dọ̀ Olódùmarè, ẹni tí ó dọ̀bálẹ̀, tí ojú rẹ̀ sì ṣí: “Mo rí i, ṣùgbọ́n kì í ṣe ìsinsin yìí. Mo kíyèsi, ṣùgbọ́n kò súnmọ́. Ìràwọ̀ kan yóò jáde láti ọ̀dọ̀ ọbu; yóò yọ jáde láti ẹli. Yóò tẹ̀ fọ́ orí , yóò sì fọ́ agbárí gbogbo ọmọ . Wọn yóò borí ; yóò ṣẹ́gun ọ̀tá rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹli yóò dàgbà nínú agbára. Olórí yóò jáde láti ọbu yóò sì pa àwọn tó ṣẹ́kù nínú ìlú náà run.” Nígbà náà ni rí ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Amaleki ni àkọ́kọ́ nínú àwọn orílẹ̀-èdè, ṣùgbọ́n yóò dahoro níkẹyìn.” Nígbà náà ní ó rí ará ó sì bẹ̀rẹ̀ òwe: “Ibùgbé rẹ ní ààbò, ìtẹ́ rẹ ni a tò sínú àpáta; síbẹ̀ ẹ̀yin ará ni yóò di píparun nígbà tí bá mú yín ní ìgbèkùn.” Nígbà náà ni ó bẹ̀rẹ̀ òwe rẹ̀: “Háà, ta ni ó lè yè nígbà tí Ọlọ́run bá ṣe èyí? Ọkọ̀ yóò wá láti ibùdókọ̀ ; wọn yóò ṣẹ́gun àti , ṣùgbọ́n àwọn náà yóò di píparun.” Nígbà náà ni dìde ó sì padà sí ilé rẹ̀, Balaki sì lọ ní ọ̀nà tirẹ̀.
Every verse in Numbers 24
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.