Proverbs 25:17

“Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ.”

Proverbs 25:17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 17 of 28 in Proverbs chapter 25 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Proverbs 25 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Wọ̀nyí ni àwọn òwe mìíràn tí pa, tí àwọn ọkùnrin ọba dà kọ. Ògo Ọlọ́run ní láti fi ọ̀rọ̀ kan pamọ́; láti rí ìdí ọ̀rọ̀ kan ni ògo àwọn ọba. Bí ọ̀run ṣe ga tó tí ayé sì jì bẹ́ẹ̀ ni ó ṣòro láti mọ èrò ọkàn ọba. Mú ìdàrọ́ kúrò lára fàdákà ohun èlò yóò sì jáde fún alágbẹ̀dẹ fàdákà. Mú ènìyàn búburú kúrò níwájú ọba a ó sì fìdí ìtẹ́ rẹ múlẹ̀ nípasẹ̀ òdodo. Má ṣe gbé ara rẹ ga níwájú ọba, má sì ṣe jìjàdù ààyè láàrín àwọn ènìyàn pàtàkì, ó sàn kí ó wí fún ọ pé, “Gòkè wá síyìn-ín,” ju wí pé kí ó dójútì ọ́ níwájú ènìyàn pàtàkì. Ohun tí o ti fi ojú ara rẹ rí má ṣe kánjú gbé e lọ sílé ẹjọ́ nítorí kí ni ìwọ yóò ṣe ní ìgbẹ̀yìn bí aládùúgbò rẹ bá dójútì ọ́? Bí o bá ń ṣe àwíjàre rẹ níwájú aládùúgbò rẹ, má ṣe tú àṣírí tí ẹlòmíràn ní lọ́dọ̀ rẹ, àìṣe bẹ́ẹ̀ ẹni tí ó gbọ́ ọ le dójútì ọ́ orúkọ búburú tí ìwọ bá sì gba kì yóò tán láéláé. Ọ̀rọ̀ tí a sọ ní àkókò tí ó yẹ ó dàbí èso wúrà nínú àpẹẹrẹ fàdákà. Bí i yẹtí wúrà tàbí ohun ọ̀ṣọ́ ti wúrà dáradára ni ìbáwí ọlọ́gbọ́n fún etí tí ó bá fetísílẹ̀. Bí títutù òjò yìnyín ní àsìkò ìkórè ni ìránṣẹ́ tí ó jẹ́ olóòtítọ́ sí àwọn tí ó rán an ó ń tu ọ̀gá rẹ̀ nínú. Bí ojú ṣíṣú àti afẹ́fẹ́ láìsí òjò ni ènìyàn tí ń yangàn nípa ẹ̀bùn tí kò fún ni. Nípa sùúrù a lè yí ọba lọ́kàn padà ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ rírọ̀ sí egungun. Bí ìwọ bá rí oyin, jẹ ẹ́ ní ìwọ̀nba bí o bá jẹ ẹ́ jù, ìwọ yóò sì bì í. Má ṣe máa lọ sí ilé aládùúgbò rẹ nígbà gbogbo tàbí kí ó máa lọ síbẹ̀ lálọ jù, yóò sì kórìíra rẹ. Bí ọ̀pá, idà tàbí ọ̀kọ̀ tí ó mú ni ènìyàn tí ó jẹ́rìí èké lòdì sí aládùúgbò rẹ̀. Bí eyín tí ó bàjẹ́ tàbí ẹsẹ̀ tí ó rọ ni ìgbẹ́kẹ̀lé lórí aláìṣòótọ́ ní àsìkò ìdààmú. Bí ẹni tí ó bọ́ra kalẹ̀ ní ọjọ́ tí òtútù mú, tàbí, bí ọtí kíkan tí a dà sí ojú ọgbẹ́, ní ẹni tí ń kọ orin fún ẹni tí ọkàn rẹ̀ bàjẹ́. Bí ebi bá ń pa ọ̀tá rẹ, fún un ní oúnjẹ jẹ; bí òǹgbẹ bá ń gbẹ ẹ́, fún un ní omi mú. Nípa ṣíṣe báyìí, ìwọ yóò wa ẹ̀yín iná lé e lórí Olúwa yóò sì san ọ ní ẹ̀san rẹ̀ fún ọ. Bí afẹ́fẹ́ gúúsù ti í mú òjò wá, bí ahọ́n tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀yìn ṣe ń mú ojú ìbínú wá. Ó sàn láti gbé ní ibi igun kan lórí òrùlé ju láti bá aya íjà gbé ilé pọ̀. Bí omi tútù sí ọkàn tí ń ṣe àárẹ̀ ni ìròyìn ayọ̀ láti ọ̀nà jíjìn. Bí ìsun tí ó di àbàtà tàbí kànga tí omi rẹ̀ bàjẹ́ ni olódodo tí ó fi ààyè gba ènìyàn búburú. Kò dára láti jẹ oyin àjẹjù, bẹ́ẹ̀ ni kò pọ́n ni lé láti máa wá ọlá fún ara ẹni. Bí ìlú tí odi rẹ̀ ti wó lulẹ̀ ni ènìyàn tí kò le kó ara rẹ̀ ní ìjánu.

Every verse in Proverbs 25

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00