Psalms 101:6

“Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí.”

Psalms 101:6 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 6 of 8 in Psalms chapter 101 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 101 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn. Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé. Èmi kì yóò gbé ohun búburú sí iwájú mi: iṣẹ́ àwọn tí ó yapa ni èmi kórìíra. Wọn kì yóò rọ̀ mọ́ mi. Agídí ọkàn yóò kúrò lọ́dọ̀ mi; èmi kì yóò mọ ènìyàn búburú. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ẹnìkejì rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀, òun ní èmi yóò gé kúrò ẹni tí ó bá gbé ojú rẹ̀ ga tí ó sì ní ìgbéraga àyà, òun ní èmi kì yóò faradà fún. Ojú mi yóò wà lára àwọn olóòtítọ́ lórí ilẹ̀, kí wọn kí ó lè máa bá mi gbé; ẹni tí ó bá n rin ọ̀nà pípé òun ni yóò máa sìn mí. Ẹni tí ó bá ń ṣe ẹ̀tàn, kì yóò gbé ilé mi, kò sí ẹni tí ń ṣèké tí yóò dúró ní iwájú mi. Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà; èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú Olúwa.

Every verse in Psalms 101

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00