Psalms 108:10

“Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí Edomu?”

Psalms 108:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 10 of 13 in Psalms chapter 108 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 108 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ọlọ́run, ọkàn mi dúró ṣinṣin èmi ó máa kọrin, èmi ó máa fi ọkàn mi kọrin. Jí ohun èlò orin àti haapu! Èmi ó jí ní kùtùkùtù, èmi ó yìn ọ́, Olúwa, nínú àwọn orílẹ̀-èdè, èmi ó kọrin rẹ nínú àwọn ènìyàn. Nítorí tí o tóbi ní àánú rẹ ju àwọn ọ̀run lọ àti òdodo rẹ dé àwọsánmọ̀. Gbé ara rẹ ga, Ọlọ́run, lórí àwọn ọ̀run, àti ògo rẹ lórí gbogbo ayé. Kí a sì lè gba àwọn olùfẹ́ rẹ là; fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ ṣe ìgbàlà, kí o sì dá mi lóhùn Ọlọ́run ti sọ̀rọ̀ láti ibi mímọ́ rẹ̀ pé, “Èmi yóò yọ̀, èmi yóò pín Ṣekemu, èmi yóò sì wọn àfonífojì kúrò. Gileadi ni tèmi, Manase ni tèmi, Efraimu ni ìbòrí mi, Juda ni olófin mi, Moabu sì ni ìkòkò ìwẹsẹ̀ mi, lórí ni èmi ó bọ́ bàtà mi sí, lórí òkè ni èmi yóò hó ìhó ayọ̀.” Ta ni yóò mú mi wá sí ìlú olódi? Ta ni yóò sìn mí wá sí ? Ìwọ Ọlọ́run ha kọ́, ìwọ tí ó ti kọ̀ wá sílẹ̀. Ọlọ́run ìwọ kì yóò bá àwọn jagunjagun wa jáde mọ́. Fún wa ní ìrànlọ́wọ́ nínú ìpọ́njú, nítorí ìrànlọ́wọ́ ènìyàn asán ni. Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.

Every verse in Psalms 108

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00