Psalms 115:10
“Ẹ̀ yin ilé Aaroni, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn.”
Psalms 115:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 10 of 18 in Psalms chapter 115 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 115 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Kì í ṣe fún wa, Olúwa kì í ṣe fún wa, ṣùgbọ́n fún orúkọ rẹ ni a fi ògo fún, fún àánú àti òtítọ́ rẹ. Torí kí ni àwọn kèfèrí yóò ṣe sọ pé, níbo ni Ọlọ́run wa wà. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wa wà lọ́run: tí ó ń ṣe èyí tí ó wù ú. Fàdákà òun wúrà ni èrè àwọn aláìkọlà, iṣẹ́ ọwọ́ ènìyàn ni. Wọ́n ní ẹnu, ṣùgbọ́n wọn kò le sọ̀rọ̀, wọ́n ní ojú, ṣùgbọ́n wọn kò fi ríran. Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbọ́rọ̀: wọ́n ní imú, ṣùgbọ́n wọn kò fi gbóòórùn. Wọ́n ní ọwọ́, ṣùgbọ́n wọn kò lò ó, wọ́n ní ẹsẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rìn; bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀ nínú òfin wọn. Àwọn tí ń ṣe wọ́n dàbí wọn; gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni olúkúlùkù ẹni tí ó gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé wọn. Ìwọ ẹli gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn Ẹ̀ yin ilé , gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ni ìrànwọ́ àti ààbò wọn. Ẹ̀ yin tí ó bẹ̀rù Olúwa, gbẹ́kẹ̀lé Olúwa: òun ní ìrànwọ́ àti ààbò wọn. Olúwa tí ń ṣe ìrántí wa; yóò bùkún ilé ẹli; yóò bùkún ilé . Ìbùkún ni fún àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa, àti kékeré àti ńlá. Olúwa yóò mú ọ pọ̀ sí i síwájú àti síwájú, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Olúwa ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa: ṣùgbọ́n ayé ló fi fún ọmọ ènìyàn. Òkú kò lè yìn Olúwa, tàbí ẹni tí ó ti lọ sí ìsàlẹ̀ ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ẹ yin Olúwa.
Every verse in Psalms 115
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.