Psalms 121:1

“Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá?”

Psalms 121:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 1 of 8 in Psalms chapter 121 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 121 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Èmi yóò gbé ojú mi sórí òkè wọ̀n-ọn-nì— níbo ni ìrànlọ́wọ́ mi yóò ti wá? Ìrànlọ́wọ́ mi tí ọwọ́ Olúwa wá, ẹni tí ó dá ọ̀run òun ayé. Òun kì yóò jẹ́ kí ẹsẹ̀ rẹ kí ó yẹ̀; ẹni tí ó pa ọ́ mọ́ kì í tòògbé. Kíyèsi, ẹni tí ń pa ẹli mọ́, kì í tòògbé bẹ́ẹ̀ ni kì í sùn. Olúwa ni olùpamọ́ rẹ; Olúwa ní òjìji rẹ ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ. Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru. Olúwa yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú ibi gbogbo yóò pa ọkàn rẹ mọ́ Olúwa yóò pa àlọ àti ààbọ̀ rẹ mọ́ láti ìgbà yìí lọ àti títí láéláé.

Every verse in Psalms 121

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00