Psalms

Psalms 123

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 123 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ìwọ ní mo gbé ojú mí sókè sí, ìwọ tí ń gbé inú ọ̀run. Kíyèsi, bí ojú àwọn ìránṣẹ́kùnrin ti máa ń wo ọwọ́ àwọn baba wọn, àti bí ojú ìránṣẹ́bìnrin ti máa ń wo ọwọ́ ìyá rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ojú wa ń wo Olúwa Ọlọ́run wa, títí yóò fi ṣàánú fún wa. Olúwa, ṣàánú fún wa, ṣàánú fún wa; nítorí tí a kún fún ẹ̀gàn púpọ̀púpọ̀. Ọkàn wa kún púpọ̀ fún ẹ̀gàn àwọn írera, àti fún ẹ̀gàn àwọn agbéraga.

Every verse in Psalms 123

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00