Psalms 129:4
“Olódodo ni Olúwa: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.””
Psalms 129:4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 4 of 8 in Psalms chapter 129 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 129 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
“Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá,” jẹ́ kí ẹli kí ó wí nísinsin yìí; “Ìgbà púpọ̀ ni wọ́n ti pọ́n mi lójú láti ìgbà èwe mi wá; síbẹ̀ wọn kò tí ì borí mi. Àwọn awalẹ̀ walẹ̀ sí ẹ̀yìn mi: wọ́n sì la aporo wọn gígùn. Olódodo ni Olúwa: ó ti ké okùn àwọn ènìyàn búburú kúrò.” Kí gbogbo àwọn tí ó kórìíra kí ó dààmú, kí wọn kí ó sì yí ẹ̀yìn padà. Kí wọn kí ó dàbí koríko orí ilẹ̀ tí ó gbẹ dànù kí ó tó dàgbàsókè, èyí tí olóko pípa kó kún ọwọ́ rẹ̀: bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ń di ìtí, kó kún apá rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn tí ń kọjá lọ kò wí pé, ìbùkún Olúwa kí ó pẹ̀lú yín: àwa ń súre fún yin ní orúkọ Olúwa.
Every verse in Psalms 129
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.