Psalms 130:1
“Láti inú ibú wá ni èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa”
Psalms 130:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 1 of 8 in Psalms chapter 130 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 130 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Láti inú ibú wá ni èmi ń ké pè é ọ́ Olúwa Olúwa, gbóhùn mi, jẹ́ kí etí rẹ kí o tẹ́ sílẹ̀ sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. Olúwa, ìbá ṣe pé kí ìwọ máa sàmì ẹ̀ṣẹ̀, Olúwa, tá ni ìbá dúró. Nítorí ìdáríjì wà lọ́dọ̀ rẹ, kí a lè máa bẹ̀rù rẹ. Èmi dúró de Olúwa, ọkàn mi dúró, àti nínú ọ̀rọ̀ rẹ ni èmi ń ṣe ìrètí. Ọkàn mi dúró de Olúwa, ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ, àní ju àwọn tí ń ṣọ́nà òwúrọ̀ lọ. Israẹli, ìwọ ní ìrètí ní ti Olúwa: nítorí pé lọ́dọ̀ Olúwa ni àánú wà, àti lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdáǹdè wà. Òun ó sì dá ẹli ní ìdè kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ gbogbo.
Every verse in Psalms 130
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.