Psalms

Psalms 136

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 136 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run àwọn ọlọ́run: nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa àwọn olúwa, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún Òun nìkan tí ń ṣiṣẹ́ ìyanu ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó fi ọgbọ́n dá ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó tẹ́ ilẹ̀ lórí omi; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó kọlu lára àwọn àkọ́bí wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì mú ẹli jáde kúrò láàrín wọn; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó pín Òkun pupa ní ìyà; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì mú ẹli kọjá láàrín rẹ̀ nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ṣùgbọ́n ó bi àti ogun rẹ̀ ṣubú nínú Òkun pupa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó sin àwọn ènìyàn rẹ̀ la aginjù já nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Fún ẹni tí ó kọlu àwọn ọba ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì pa àwọn ọba olókìkí nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Sihoni, ọba àwọn ará nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Àti , ọba Baṣani; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì fi ilẹ̀ wọn fún ni ní ìní, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ìní fún ẹli, ìránṣẹ́ rẹ̀, nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹni tí ó rántí wa ní ìwà ìrẹ̀lẹ̀ wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ó sì dá wa ní ìdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹni tí ó fi oúnjẹ fún àwọn ẹ̀dá gbogbo nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé. Ẹ fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run ọ̀run; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

Every verse in Psalms 136

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00