Psalms

Psalms 137

Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible · tap any highlighted word for context

Psalms 137 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ní ẹ̀bá odò , níbẹ̀ ni àwa gbé jókòó àwa sì sọkún nígbà tí àwa rántí . Àwa fi dùùrù wa kọ́ sí orí igi wílò, tí ó wà láàrín rẹ̀. Nítorí pé níbẹ̀ ni àwọn tí ó kó wa ní ìgbèkùn béèrè orin lọ́wọ́ wa, àti àwọn tí ó ni wá lára béèrè ìdárayá; wọn wí pé, “Ẹ kọ orin kan fún wa!” Àwa ó ti ṣe kọ orin Olúwa ní ilẹ̀ àjèjì Jerusalẹmu, bí èmi bá gbàgbé rẹ jẹ́ kí ọwọ́ ọ̀tún mi kí ó gbàgbé ìlò rẹ̀. Bí èmi kò bá rántí rẹ, jẹ́ kí ahọ́n mi kí ó lẹ̀ mọ́ èrìgì mi; bí èmi kò bá fi ẹmu ṣáájú olórí ayọ̀ mi gbogbo. Olúwa rántí ọjọ́ ẹmu, lára àwọn ọmọ , àwọn ẹni tí ń wí pé, “Wó o palẹ̀, wó o palẹ̀ dé ìpìlẹ̀ rẹ̀!” Ìwọ, ọmọbìnrin , ẹni tí a ó parun; ìbùkún ni fún ẹni tí ó san án fún ọ bí ìwọ ti rò sí wa. Ìbùkún ni fún ẹni tí ó mú ọmọ wẹ́wẹ́ rẹ tí ó sì fi wọ́n ṣán òkúta.

Every verse in Psalms 137

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00