Psalms 144:3
“Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un, tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀?”
Psalms 144:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 3 of 15 in Psalms chapter 144 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 144 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ìyìn sí Olúwa àpáta mi, ẹni tí ó kọ́ ọwọ́ mi fún ogun, àti ìka mi fún ìjà. Òun ni Ọlọ́run ìfẹ́ mi àti odi alágbára mi, ibi gíga mi àti olùgbàlà mi, asà mi, ẹni tí èmi gbẹ́kẹ̀lé, ẹni tí ó tẹrí àwọn ènìyàn ba lábẹ́ mi. Olúwa, kí ni ènìyàn tí ìwọ fi ń ṣàníyàn fún un, tàbí ọmọ ènìyàn tí ìwọ fi ń ronú nípa rẹ̀? Ènìyàn rí bí èmi; ọjọ́ rẹ̀ rí bí òjìji tí ń kọjá lọ. Tẹ ọ̀run rẹ ba, Olúwa, kí o sì sọ̀kalẹ̀; tọ́ àwọn òkè ńlá wọn yóò sí rú èéfín. Rán mọ̀nàmọ́ná kí ó sì fọ́n àwọn ọ̀tá ká; ta ọfà rẹ kí ó sì dà wọ́n rú. Na ọwọ́ rẹ sílẹ̀ láti ibi gíga; gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò nínú omi ńlá: kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì. Ẹnu ẹni tí ó kún fún èké ẹni tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ jẹ́ ìrẹ́jẹ. Èmi yóò kọ orin tuntun sí ọ Ọlọ́run; lára ohun èlò orin olókùn mẹ́wàá èmi yóò kọ orin sí ọ. Òun ni ó fi ìgbàlà fún àwọn ọba, ẹni tí ó gba ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ idà ìpanilára. Lọ́wọ́ pípanirun. Gbà mí kí o sì yọ mí nínú ewu kúrò lọ́wọ́ àwọn ọmọ àjèjì tí ẹnu wọn kún fún èké, tí ọwọ́ ọ̀tún wọn jẹ́ ọwọ́ ọ̀tún èké. Kí àwọn ọmọkùnrin wa kí ó dàbí igi gbígbìn tí ó dàgbà ni ìgbà èwe wọn, àti ọmọbìnrin wa yóò dàbí òpó ilé tí a ṣe ọ̀nà sí bí àfarawé ààfin. Àká wa yóò kún pẹ̀lú gbogbo írúú oúnjẹ àgùntàn wa yóò pọ̀ si ní ẹgbẹ̀rún, ní ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní oko wa: àwọn màlúù wa yóò ru ẹrù wúwo kí ó má sí ìkọlù, kí ó má sí ìkólọ sí ìgbèkùn, kí ó má sí i igbe ìpọ́njú ní ìgboro wa. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà tí ó wà ní irú ipò bẹ́ẹ̀, ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn náà, tí ẹni tí Ọlọ́run Olúwa ń ṣe.
Every verse in Psalms 144
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.