Psalms 149:1

“Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́.”

Psalms 149:1 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 1 of 9 in Psalms chapter 149 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 149 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹ fi ìyìn fún Olúwa. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa. Ẹ yìn ín ní àwùjọ àwọn ènìyàn mímọ́. Jẹ́ kí ẹli kí ó ní inú dídùn sí ẹni tí ó dá a jẹ́ kí àwọn ọmọ kí ó ní ayọ̀ nínú ọba wọn. Jẹ́ kí wọn kí ó fi ijó yin orúkọ rẹ̀ jẹ́ kí wọn kí ó fi ohun èlò orin kọrin ìyìn sí i. Nítorí Olúwa ní inú dídùn sí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó fi ìgbàlà dé àwọn írẹ̀lẹ̀ ládé. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mímọ́ kí ó yọ̀ nínú ọlá rẹ̀ kí wọn kí ó máa kọrin fún ayọ̀ ní orí ibùsùn wọn. Kí ìyìn Ọlọ́run kí ó wà ní ẹnu wọn àti idà olójú méjì ní ọwọ́ wọn. Láti gba ẹ̀san lára àwọn orílẹ̀-èdè, àti ìjìyà lára àwọn ènìyàn, láti fi ẹ̀wọ̀n de àwọn ọba wọn àti láti fi ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ irin de àwọn ọlọ́lá wọn. Láti ṣe ìdájọ́ tí àkọsílẹ̀ rẹ̀ sí wọn èyí ni ògo àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.

Every verse in Psalms 149

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00