Psalms 17:13
“Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ.”
Psalms 17:13 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 13 of 15 in Psalms chapter 17 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 17 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Gbọ́, Olúwa, ẹ̀bẹ̀ òtítọ́ mi; fi etí sí igbe mi. Tẹ́tí sí àdúrà mi tí kò ti ètè ẹ̀tàn jáde. Kí ìdáláre mi wá láti ọ̀dọ̀ rẹ; kí ojú rẹ kí ó rí ohun tí ó tọ́. Ìwọ ti dán àyà mi wò, ìwọ sì bẹ̀ mí wò ní òru, o sì ti wádìí mi, ìwọ kì yóò rí ohunkóhun èmi ti pinnu pé, ẹnu mi kì yóò ṣẹ̀. Bí ó ṣe ti iṣẹ́ ènìyàn nípa ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ, èmi ti pa ara mi mọ́ kúrò ní ọ̀nà àwọn ìkà. Ìrìn mí ti jẹ mọ́ ọ̀nà rẹ; ẹsẹ̀ mi kì yóò yọ̀. Èmi ké pè ọ́, Ọlọ́run, nítorí tí ìwọ yóò dá mi lóhùn dẹ etí rẹ sí mi kí o sì gbọ́ àdúrà mi. Fi ìṣeun ìyanu ìfẹ́ ńlá rẹ hàn ìwọ tí ó fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gba àwọn tí ó gbẹ́kẹ̀lé ọ là lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. Pa mí mọ́ bí ẹyin ojú rẹ; fi mí pamọ́ sí abẹ́ òjìji ìyẹ́ apá rẹ, lọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú tí ń fóròó mi, kúrò ní ọwọ́ àwọn ọ̀tá apani tí ó yí mi ká. Wọ́n pa ọkàn aláìláàánú wọn mọ́, wọ́n sì fi ẹnu wọn sọ̀rọ̀ ìgbéraga. Wọ́n sì mú mi mọ́lẹ̀, wọ́n sì yí mi ká, pẹ̀lú ojú ìṣọ́ra láti ṣọ́ mi sílẹ̀. Wọn dàbí i kìnnìún tí ebi ń pa fún ìjẹ, àní bí kìnnìún ńlá tí ó ń ba níbi ìkọ̀kọ̀. Dìde, Olúwa, dojúkọ wọ́n, rẹ̀ wọ́n sílẹ̀; gbà mí sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni búburú nípa idà rẹ. Olúwa, nípa ọwọ́ rẹ, gbà mí kúrò lọ́wọ́ irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀, kúrò lọ́wọ́ àwọn ènìyàn ayé yìí, tí èrè wọn wà nínú ayé yìí. Ìwọ ń pa ebi àwọn tí ìwọ fẹ́ràn lẹ́nu mọ́; àwọn ọmọ wọn sì ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì kó ọrọ̀ jọ fún àwọn ọmọ wọn. Ṣùgbọ́n ní tèmi, èmi yóò máa wo ojú rẹ ní òdodo; nígbà tí èmi bá jí, èmi yóò ní ìtẹ́lọ́rùn nígbà tí èmi bá rí àwòrán rẹ.
Every verse in Psalms 17
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.