Psalms 20:8

“Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin.”

Psalms 20:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 8 of 9 in Psalms chapter 20 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 20 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Kí Olúwa kí ó gbóhùn rẹ ní ọjọ́ ìpọ́njú; kí orúkọ Ọlọ́run ọbu kí ó dáàbò bò ọ́. Kí ó rán ìrànlọ́wọ́ sí ọ, láti ibi mímọ́ kí ó sì tì ọ́ lẹ́yìn láti wá. Kí ó sì rántí gbogbo ẹbọ rẹ kí ó sì gba ẹbọ sísun rẹ. . Kí ó fi fún ọ gẹ́gẹ́ bi ti èrò ọkàn rẹ kí ó sì mú gbogbo ìmọ̀ rẹ ṣẹ. Àwa yóò hó fún ayọ̀ nígbà tí o bá di aṣẹ́gun àwa yóò gbé àsíá wa sókè ní orúkọ Ọlọ́run wa. Kí Olúwa kí ó mú gbogbo ìbéèrè rẹ̀ ṣẹ. Nísinsin yìí, èmi mọ̀ wí pé, Olúwa pa ẹni àmì òróró rẹ̀ mọ́. Yóò gbọ́ láti ọ̀run mímọ́ rẹ̀ wá pẹ̀lú agbára ìgbàlà ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé kẹ̀kẹ́, àwọn mìíràn gbẹ́kẹ̀ wọn lé ẹṣin, ṣùgbọ́n àwa gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwa Ọlọ́run wa. Wọ́n wólẹ̀, ní eékún, wọ́n sì ṣubú, ṣùgbọ́n àwa dìde, a sì dúró ṣinṣin. Olúwa, fi ìṣẹ́gun fún ọba! Dá wa lóhùn nígbà tí a bá ń kígbe pè!

Every verse in Psalms 20

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00