Psalms 21:12
“Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà.”
Psalms 21:12 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 12 of 13 in Psalms chapter 21 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 21 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Háà! Olúwa, ọba yóò yọ̀ nínú agbára rẹ, àti ní ìgbàlà rẹ, yóò ti yọ̀ pẹ́ tó! Nítorí pé ìwọ ti fi ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò sì dùn ún ní ìbéèrè ẹnu rẹ̀. . Ìwọ ti fi àwọn ìbùkún oore kò ó ni ọ̀nà ìwọ fi adé wúrà dé e ní orí. Ó béèrè fún ìyè, ìwọ sì fi fún un, àní ọjọ́ gígùn títí ayérayé. Ògo rẹ̀ pọ̀ nípasẹ̀ ìṣẹ́gun tí o fi fún un; ìwọ sì jẹ́ kí iyì ọláńlá rẹ̀ wà lára rẹ. Dájúdájú, ìwọ ti fi ìbùkún ayérayé fún un: ìwọ sì mú inú rẹ̀ dùn pẹ̀lú ayọ̀ ojú u rẹ̀. Ọba ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Olúwa; nípasẹ̀ ìfẹ́ Ọ̀gá-ògo tí kì í kùnà kì yóò sípò padà. Ọwọ́ rẹ yóò wá gbogbo àwọn ọ̀tá a rẹ rí; ọwọ́ ọ̀tún rẹ yóò wá àwọn tí o kórìíra rẹ rí. Nígbà tí ìwọ bá yọ ìwọ yóò mú wọn dàbí iná ìléru. Olúwa yóò gbé wọn mì nínú ìbínú rẹ̀, àti pé iná rẹ̀ yóò jó wọn run. Ìwọ yóò pa ìrandíran wọn run kúrò lórí ilẹ̀, àti irú-ọmọ wọn kúrò láàrín àwọn ọmọ ènìyàn. Bí o tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n ro èrò ibi sí ọ wọ́n sì ń pète ìwà ìkà, wọn kì yóò ṣe àṣeyọrí. Nítorí pé ìwọ yóò mú wọn yí ẹ̀yìn wọn padà nígbà tí o bá pinnu láti ta wọ́n ní ọfà. Gbígbéga ni ọ́ Olúwa, nínú agbára rẹ; a ó kọrin, a ó yín agbára a rẹ̀.
Every verse in Psalms 21
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.