Psalms 23:4

“Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú.”

Psalms 23:4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 4 of 6 in Psalms chapter 23 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 23 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Olúwa ni olùṣọ́ èmi àgùntàn rẹ̀, èmi kì yóò ṣe aláìní. Ó mú mi dùbúlẹ̀ sí ibi pápá oko tútù, Ó mú mi lọ sí ibi omi dídákẹ́ rọ́rọ́, Ó mú ọkàn mi padà bọ̀ sípò. Ó mú mi lọ sí ọ̀nà òdodo nítorí orúkọ rẹ̀. Bí mo tilẹ̀ ń rìn láàrín àfonífojì òjìji ikú, èmi kì yóò bẹ̀rù ibi kan, nítorí ìwọ wà pẹ̀lú mi; ọ̀gọ rẹ àti ọ̀pá à rẹ, wọ́n ń tù mí nínú. Ìwọ tẹ́ tábìlì oúnjẹ sílẹ̀ níwájú mi ní ojú àwọn ọ̀tá à mi. Ìwọ ta òróró sí mi ní orí; ago mí sì kún àkúnwọ́sílẹ̀. Nítòótọ́, ìre àti àánú ni yóò máa tọ̀ mí lẹ́yìn ní ọjọ́ ayé è mi gbogbo, èmi yóò sì máa gbé inú ilé Olúwa títí láéláé.

Every verse in Psalms 23

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00