Psalms 28:8
“Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀.”
Psalms 28:8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 8 of 9 in Psalms chapter 28 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 28 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Ìwọ Olúwa, mo ké pe àpáta mi. Má ṣe kọ etí dídi sí mi. Tí ìwọ bá dákẹ́ sí mi, èmí yóò dàbí àwọn tí ó lọ sí ọ̀gbun. Gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi fún àánú, bí mo ṣe ń ké pè ọ́ fún ìrànlọ́wọ́, bí mo ṣe gbé àwọn ọwọ́ mi sókè sí Mímọ́ rẹ Jùlọ. Má ṣe fà mí lọ pẹ̀lú ènìyàn búburú àti, pẹ̀lú àwọn íṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, tí ń sọ̀rọ̀ àlàáfíà sí aládùúgbò wọn ṣùgbọ́n tí ìwà ìkà ń bẹ nínú wọn. San ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn àti fún iṣẹ́ ibi wọn; gba ẹ̀san wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ wọn; kí o sì san ẹ̀san wọn bí ó ti tọ́. Nítorí pé wọn kò ka iṣẹ́ Olúwa sí, tàbí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ òun ó rún wọn wọlẹ̀ kì yóò sì gbé wọn ró mọ́. Alábùkún fún ni Olúwa! Nítorí pé ó ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi. Olúwa ni agbára mi àti asà mi; nínú rẹ̀ ni mo gbẹ́kẹ̀lé; àní, ó sì ràn mí lọ́wọ́. Ọkàn mi sì gbé sókè fún ayọ̀ àní pẹ̀lú orin mi mo fi ọpẹ́ fún un. Olúwa ni agbára àwọn ènìyàn rẹ̀ òun ni odi ìgbàlà àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀. Ìwọ gba àwọn ènìyàn rẹ là, kí o sì bùkún àwọn ajogún rẹ; di olùṣọ́-àgùntàn wọn, kí o sì gbé wọn lékè títí ayérayé.
Every verse in Psalms 28
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.