Saamu

Saamu 48

Psalm 48 in Yoruba and English (KJV) · Orin Dafidi 48Tap any highlighted word for context

About this Psalm

The Psalm heading names the sons of Korah as its authors. This is a praise Psalm that celebrates Zion as the city of the great King who defends his people.

Saamu 48 — Scripture text (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀.

KJV verse 1: Great is the LORD, and greatly to be praised in the city of our God, in the mountain of his holiness.

Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè , ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá.

KJV verse 2: Beautiful for situation, the joy of the whole earth, is mount Zion, on the sides of the north, the city of the great King.

Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.

KJV verse 3: God is known in her palaces for a refuge.

Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ.

KJV verse 4: For, lo, the kings were assembled, they passed by together.

Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ.

KJV verse 5: They saw it, and so they marvelled; they were troubled, and hasted away.

Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí.

KJV verse 6: Fear took hold upon them there, and pain, as of a woman in travail.

Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi ṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn.

KJV verse 7: Thou breakest the ships of Tarshish with an east wind.

Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ìlú Ọlọ́run wa, Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. .

KJV verse 8: As we have heard, so have we seen in the city of the LORD of hosts, in the city of our God: God will establish it for ever. Selah.

Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ.

KJV verse 9: We have thought of thy lovingkindness, O God, in the midst of thy temple.

Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run, ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé, ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo.

KJV verse 10: According to thy name, O God, so is thy praise unto the ends of the earth: thy right hand is full of righteousness.

Jẹ́ kí òkè kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ.

KJV verse 11: Let mount Zion rejoice, let the daughters of Judah be glad, because of thy judgments.

Rìn kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀.

KJV verse 12: Walk about Zion, and go round about her: tell the towers thereof.

Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀.

KJV verse 13: Mark ye well her bulwarks, consider her palaces; that ye may tell it to the generation following.

Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

KJV verse 14: For this God is our God for ever and ever: he will be our guide even unto death.

Every verse in Saamu 48

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

KJV: public domain

Most-read Psalms in Yoruba

Saamu 480:00 / 0:00