Psalms 48:3

“Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára.”

Psalms 48:3 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 3 of 14 in Psalms chapter 48 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 48 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹni ńlá ní Olúwa, tí ó sì yẹ láti máa yìn ní ìlú Ọlọ́run wa, lórí òkè mímọ́ rẹ̀. Ó dára nínú ipò ìtẹ́ rẹ̀, ayọ̀ gbogbo ayé, òkè , ní ìhà àríwá ní ìlú ọba ńlá. Ọlọ́run wà nínú ààbò ààfin rẹ̀; ó fi ara rẹ̀ hàn láti jẹ́ odi alágbára. Nígbà tí àwọn ọba kógun jọ pọ̀, wọ́n jùmọ̀ ń kọjá lọ. Wọn rí i, bẹ́ẹ̀ ni ẹnu sì yà wọ́n, a yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n yára lọ. Ẹ̀rù sì bà wọ́n níbẹ̀, ìrora gẹ́gẹ́ bí obìnrin tí ó wà nínú ìrọbí. Ìwọ bà wọ́n jẹ́ gẹ́gẹ́ bí ọkọ̀ orí omi ṣiṣi, wọ́n fọ́nká láti ọwọ́ ìjì ìlà-oòrùn. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa rí, ní inú Olúwa àwọn ọmọ-ogun ní ìlú Ọlọ́run wa, Ọlọ́run jẹ́ kí ó wà ní abẹ́ ààbò títí láéláé. . Láàrín tẹmpili rẹ, Ọlọ́run, àwa ti ń sọ ti ìṣeun ìfẹ́ rẹ. Gẹ́gẹ́ bí orúkọ rẹ Ọlọ́run, ìyìn rẹ̀ dé òpin ayé, ọwọ́ ọ̀tún rẹ kún fún òdodo. Jẹ́ kí òkè kí ó yọ̀ kí inú àwọn ọmọbìnrin kí ó dùn nítorí ìdájọ́ rẹ. Rìn kiri lọ yíká rẹ̀, ka ilé ìṣọ́ rẹ̀. Kíyèsi odi rẹ̀, kíyèsi àwọn ààfin rẹ̀ kí ẹ̀yin lè máa wí fún ìran tí ń bọ̀. Nítorí Ọlọ́run yìí Ọlọ́run wà ní títí ayé, Òun ni yóò ṣe amọ̀nà wa títí dè òpin ayé.

Every verse in Psalms 48

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00