Psalms 49:10

“Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn.”

Psalms 49:10 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 10 of 20 in Psalms chapter 49 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 49 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹ gbọ́ èyí, gbogbo ènìyàn! Ẹ fi etí sí i, gbogbo ẹ̀yin aráyé. Àti ẹni tí ó ga àti ẹni tí ó kéré tálákà àti ọlọ́lá pẹ̀lú! Ẹnu mi yóò sọ̀rọ̀ ọgbọ́n, èrò láti ọkàn mi yóò mú òye wá èmi yóò dẹ etí mi sílẹ̀ sí òwe, èmi yóò ṣí ọ̀rọ̀ ìkọ̀kọ̀ mi sílẹ̀ lójú okùn dùùrù. Èéṣe ti èmi yóò bẹ̀rù nígbà tí ọjọ́ ibi dé? Nígbà tí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ajinnilẹ́sẹ̀ mi yí mi ká, àwọn tí o gbẹ́kẹ̀lé ọrọ̀ wọn, tí wọn sì ń ṣe ìlérí ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ wọn. Kò sí ọkùnrin tí ó lè ra ẹ̀mí ẹnìkejì rẹ̀ padà tàbí san owó ìràpadà fún Ọlọ́run. Nítorí ìràpadà fún ẹni jẹ́ iyebíye kò sì sí iye owó tó tó fún sísan rẹ̀, ní ti kí ó máa wà títí ayé láìrí isà òkú. Nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn rí ọkùnrin ọlọ́gbọ́n tí ó kú, bẹ́ẹ̀ ni aṣiwèrè àti aláìlọ́gbọ́n pẹ̀lú ṣègbé wọ́n sì fi ọrọ̀ wọn sílẹ̀ fún ẹlòmíràn. Ibojì wọn ni yóò jẹ́ ilé wọn láéláé, ibùgbé wọn láti ìrandíran, wọn sọ orúkọ ilẹ̀ wọn ní orúkọ ara wọn. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí o wà nínú ọlá kò dúró pẹ́ ó sì dàbí ẹranko tí ó ṣègbé. Èyí ni òtítọ́ àwọn ènìyàn tí ó gbàgbọ́ nínú ara wọn, àti àwọn tí ń tẹ̀lé wọn, tí ó gba ọ̀rọ̀ wọn. . Gẹ́gẹ́ bí àgùntàn ni a tẹ́ wọn sínú isà òkú ikú yóò jẹun lórí wọn; ẹni tí ó dúró ṣinṣin ni yóò, jẹ ọba lórí wọn ní òwúrọ̀. Ẹwà wọn yóò díbàjẹ́, isà òkú ni ibùgbé ẹwà wọn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò ra ọkàn mi padà kúrò nínú isà òkú, yóò gbé mi lọ sọ́dọ̀ òun fún rara rẹ̀. Má ṣe bẹ̀rù nígbà tí ẹnìkan bá di ọlọ́rọ̀. Nígbà tí ìyìn ilé rẹ̀ ń pọ̀ sí i. Nítorí kì yóò mú ohun kan lọ nígbà tí ó bá kú, ògo rẹ̀ kò ní bá a sọ̀kalẹ̀ sí ipò òkú. Nígbà tí ó wà láyé, ó súre fún ọkàn ara rẹ̀. Àwọn ènìyàn yìn ọ́ nígbà tí ìwọ ṣe rere. Òun yóò lọ sí ọ̀dọ̀ ìran àwọn baba rẹ̀ àwọn tí ki yóò ri ìmọ́lẹ̀ ayé. Ọkùnrin tí ó ní ọlá tí kò ní òye dàbí ẹranko tí ó ṣègbé.

Every verse in Psalms 49

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00