Psalms 52:9
“Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí orúkọ rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.”
Psalms 52:9 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 9 of 9 in Psalms chapter 52 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 52 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe féfé nínú ìwà ìkà, ìwọ alágbára ọkùnrin? Èéṣe tí ìwọ fi ń gbéraga nígbà gbogbo, ìwọ ẹni ẹ̀gàn níwájú Ọlọ́run? Ahọ́n rẹ̀ ń gbìmọ̀ ìparun; ó dàbí abẹ mímú, ìwọ ẹni tí ń hùwà ẹ̀tàn. Ìwọ fẹ́ràn ibi ju ìre lọ, àti èké ju kí ó sọ òtítọ́ lọ. Ìwọ fẹ́ràn ọ̀rọ̀ ìpanilára gbogbo, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn! Ọlọ́run yóò sì lù ọ́ bolẹ̀ láéláé, yóò sì dì ọ́ mú, yóò sì já ọ kúrò ni ibùjókòó rẹ, yóò sì fà ọ́ tu kúrò lórí ilẹ̀ alààyè. . Àwọn olódodo yóò rí, wọn yóò sì bẹ̀rù wọn yóò sì rẹ́rìn-ín rẹ̀, wí pé, “Èyí ni ọkùnrin náà ti kò fi Ọlọ́run ṣe agbára rẹ̀, bí kò ṣe ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọrọ̀ rẹ̀ ni ó gbẹ́kẹ̀lé, ó sì mu ara rẹ̀ le nínú ìwà búburú rẹ̀.” Ṣùgbọ́n èmi dàbí igi tí ó gbilẹ̀ nínú ilé Ọlọ́run; èmi gbẹ́kẹ̀lé ìfẹ́ Ọlọ́run tí kì í kùnà láé àti láéláé. Èmi yóò yìn ọ títí fún ohun tí ó ti ṣe; èmi ní ìrètí nínú orúkọ rẹ, nítorí orúkọ rẹ dára. Èmi yóò yìn ọ́ níwájú àwọn ènìyàn mímọ́.
Every verse in Psalms 52
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.