Psalms 53:4
“Ṣé àwọn oníṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀? Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run?”
Psalms 53:4 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible
Verse 4 of 6 in Psalms chapter 53 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.
Psalms 53 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)
Aṣiwèrè wí ní ọkàn rẹ̀ pé, “Ọlọ́run kò sí.” Wọ́n bàjẹ́, gbogbo ọ̀nà wọn sì burú; kò sì ṣí ẹnìkan tí ń ṣe rere. Ọlọ́run bojú wo ilẹ̀ láti ọ̀run sórí àwọn ọmọ ènìyàn, láti wò bóyá ẹnìkan wà, tí ó ní òye, tí ó sì ń wá Ọlọ́run. Gbogbo ènìyàn tí ó ti yí padà, wọ́n ti parapọ̀ di ìbàjẹ́; kò sí ẹnìkan tí ó ń ṣe rere, kò sí ẹnìkan. Ṣé àwọn íṣẹ́ búburú kò ní ìmọ̀? Àwọn ẹni tí ń jẹ ènìyàn mi, bí ẹni jẹun tí wọn kò sì pe Ọlọ́run? Níbẹ̀ ni ìwọ gbé wà ní ìbẹ̀rù ńlá níbi tí ẹ̀rù kò gbé sí, nítorí Ọlọ́run tí fọ́n egungun àwọn tí ó dó tì ọ́ ká; ìwọ tí dójútì wọ́n, nítorí Ọlọ́run ti kẹ́gàn wọn. Ìgbàlà ẹli ìbá jáde wá láti ! Nígbà tí Ọlọ́run bá mú ohun ìní àwọn ènìyàn rẹ̀ padà, jẹ́ kí ọbu yọ̀ kí inú ẹli sì máa dùn!
Every verse in Psalms 53
Chapter navigation
Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.