Psalms 57:11

“Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ; kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.”

Psalms 57:11 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 11 of 11 in Psalms chapter 57 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 57 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ṣàánú fún mi, Ọlọ́run, ṣàánú fún mi, nítorí nínú rẹ ni ààbò ọkàn mí wà. Èmi o fi ààbò mí sí ibi ìyẹ́ apá rẹ títí tí ewu yóò fi kọjá lọ. Mo kígbe sókè sí Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ, sí Ọlọ́run tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ fún mi. Òun yóò ránṣẹ́ láti ọ̀run wá, yóò sì gbà mí, bí ẹni tí ń fẹ́ gbé mi mì tilẹ̀ ń kẹ́gàn mi. Ọlọ́run yóò rán àánú rẹ̀ àti òdodo rẹ̀ jáde. Mo wà ní àárín àwọn kìnnìún; mo dùbúlẹ̀ ni abẹ́ àwọn ẹ̀dá búburú, àwọn ènìyàn tí eyín wọn dàbí ọ̀kọ̀ àti ọfà ẹni tí ahọ́n rẹ̀ jẹ́ idà mímú. Kí a yìn ọ́ Ọlọ́run, ju ọ̀run lọ, kí ògo rẹ kò ju ti gbogbo ayé lọ. Wọ́n ti ta àwọ̀n sílẹ̀ fún ẹsẹ̀ mi: a tẹ orí ọkàn mi ba nínú ìtìjú, wọ́n gbẹ́ kòtò sí ọ̀nà mi: ṣùgbọ́n wọ́n ti jì síbẹ̀ fún ara wọn. Ọkàn mi ti múra Ọlọ́run; ọkàn mi ti múra, èmi ó kọrin, èmi ó si máa kọrin ìyìn. Jí, ìwọ ọkàn mi! Jí, ohun orin èlò àti dùùrù! Èmi tìkára mi, yóò sì jí ní kùtùkùtù. Èmi ó máa yìn ọ́, Olúwa, láàrín àwọn orílẹ̀-èdè; èmi ó máa kọrin sí ọ láàrín àwọn ènìyàn. Nítorí títóbi ní ìfẹ́ rẹ, tí ó dé ọ̀run; òtítọ́ rẹ tàn dé àwọsánmọ̀. Gbígbéga ni ọ́, Ọlọ́run, ju àwọn ọ̀run lọ; kí ògo rẹ kí ó ju gbogbo ayé lọ.

Every verse in Psalms 57

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00