Psalms 78:16

“Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò.”

Psalms 78:16 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 16 of 72 in Psalms chapter 78 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 78 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Ẹ̀yin ènìyàn mi, ẹ gbọ́ ẹ̀kọ́ mi; tẹ́tí rẹ sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. Èmi ó la ẹnu mi ní òwe, èmi o sọ ohun ìkọ̀kọ̀, ohun ti ọjọ́ pípẹ́; ohun tí a ti gbọ́ tí a sì ti mọ̀, ohun tí àwọn baba wa ti sọ fún wa. Àwa kì yóò pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ, ní fífi ìyìn Olúwa, àti ipa rẹ̀ àti iṣẹ́ ìyanu tó ti ṣe hàn fún ìran tí ń bọ̀. Ó gbé ẹ̀rí kalẹ̀ ní ọbu o sì fìdí àṣẹ múlẹ̀ ní ẹli, èyí tí ó pàṣẹ fún àwọn baba ńlá wa láti kọ́ àwọn ọmọ wọn, nítorí náà, àwọn ìran tí ń bọ̀ yóò mọ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ tí a kò tí ì bí tí yóò dìde tí wọn yóò sọ fún àwọn ọmọ wọn. Nígbà náà ni wọ́n ò fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọn sínú Ọlọ́run wọn kò sì ní gbàgbé iṣẹ́ Ọlọ́run ṣùgbọ́n wọn ó pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Kí wọn kí ó má ṣe dàbí àwọn baba ńlá wọn, ìran alágídí àti ọlọ́tẹ̀, ìran tí ọkàn wọn kò ṣọ òtítọ́ si olóore, àti ẹ̀mí ẹni tí kò bá Ọlọ́run dúró ṣinṣin. Àwọn ọkùnrin , tí ó há mọ́ ọ tí wọ́n mú ọrun, wọ́n yípadà ní ọjọ́ ogun Wọn kò pa májẹ̀mú Ọlọ́run mọ́ wọn sì kọ̀ láti máa gbé nínú òfin rẹ̀. Wọ́n gbàgbé ohun tí ó ti ṣe, àwọn ìyanu tí ó ti fihàn wọ́n. Ó ṣe ìyanu níwájú àwọn baba wọn ní ilẹ̀ , ní agbègbè Ṣoani. Ó pín òkun ní yà, ó sì mú wọn kọjá Ó mù kí omi náà dúró bi odi gíga. Ní ọ̀sán, ó fi ìkùùkuu àwọsánmọ̀ ṣe amọ̀nà wọn àti ní gbogbo òru pẹ̀lú ìmọ́lẹ̀ iná. Ó sán àpáta ní aginjù ó sì fún wọn ní omi mímu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ bí ẹni pé láti inú ibú wá. Ó mú ìṣàn omi jáde láti inú àpáta omi ṣíṣàn sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí odò. Wọ́n sì tún tẹ̀síwájú láti dẹ́ṣẹ̀ sí i ní ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo ní aginjù. Wọ́n mọ̀ ọ́n mọ̀ dán Ọlọ́run wò nípa bíbéèrè fún oúnjẹ tí wọn bẹ̀bẹ̀ fún. Wọ́n sọ̀rọ̀-òdì sí Ọlọ́run, wí pé “Ọlọ́run ha lè tẹ́ tábìlì ní aginjù? Nígbà tí ó lu àpáta, omi tú jáde, odò sì sàn lọ́pọ̀lọ́pọ̀ ṣùgbọ́n òun ha lè fún wa lóúnjẹ ó ha le pèsè ẹran fún àwọn ènìyàn rẹ̀?” Nígbà tí Olúwa gbọ́ wọn, ó bínú gidigidi; iná rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sí ọbu, ìbínú rẹ̀ sì rú sí ẹli, nítorí wọn kò gba Ọlọ́run gbọ́, wọn kò sì gbẹ́kẹ̀lé ìgbàlà rẹ̀. Síbẹ̀ ó pàṣẹ fún ìràwọ̀ ojú ọ̀run, ó sì ṣí ìlẹ̀kùn ọ̀run sílẹ̀; Ó rọ fún àwọn ènìyàn láti jẹ, ó fún wọn ní ọkà láti ọ̀run. Àwọn ènìyàn jẹ oúnjẹ àwọn angẹli; Ó fún wọn ní oúnjẹ ní àjẹyó, Ó mú afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn láti ọ̀run wá ó mú afẹ́fẹ́ gúúsù wá nípa agbára rẹ̀. Ó rọ òjò ẹran sílẹ̀ sórí wọn bí erùpẹ̀ ilẹ̀, àti ẹyẹ abìyẹ́ gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí òkun Ó jẹ́ kí wọn jáde ní ibùdó wọn, yíká àgọ́ wọn. Wọ́n jẹ, wọ́n sì yó jọjọ nítorí ó ti fún wọn ní ohun tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún. Ṣùgbọ́n wọn kò kúrò nínú oúnjẹ tí wọn fìtara bẹ̀bẹ̀ fún, nígbà tí oúnjẹ wọn sì wà ní ẹnu wọn, ìbínú Ọlọ́run dìde sí wọn ó pa àwọn tí ó jùlọ nínú wọn, ó sì lu àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹli bolẹ̀. Nínú gbogbo ìwọ̀nyí, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ síwájú; nínú gbogbo iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, wọ́n kò gbàgbọ́. O fi òpin sí ayé wọn nínú asán àti ọdún wọn nínú ìpayà. Nígbàkígbà tí Ọlọ́run bá pa wọ́n, wọn yóò wá a kiri; wọn yóò fi ìtara yípadà sí i. Wọ́n rántí pé Ọlọ́run ní àpáta wọn; wí pé Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo jùlọ ni olùràpadà àpáta wọn. Ṣùgbọ́n nígbà náà ni wọ́n yóò pọ́n ọn pẹ̀lú ẹnu wọ́n wọ́n fi ahọ́n wọ́n purọ́ fún un; ọkàn wọn kò sòtítọ́ sí i, wọn kò jẹ́ olódodo sí májẹ̀mú rẹ̀. Síbẹ̀ ó ṣàánú; ó dárí àìṣedéédéé wọn jì òun kò sì pa wọ́n run nígbà púpọ̀ ló ń yí ìbínú rẹ̀ padà kò sì ru ìbínú rẹ̀ sókè Ó rántí pé ẹlẹ́ran ara ni wọ́n, afẹ́fẹ́ tó ń kọjá tí kò lè padà. Nígbà gbogbo ní wọn ń ṣọ̀tẹ̀ sí i ní aginjù wọn mú un bínú nínú ilẹ̀ tí ó di ahoro! Síwájú àti síwájú wọ́n dán Ọlọ́run wò; wọ́n mú ẹni mímọ́ ẹli bínú. Wọ́n kò rántí agbára rẹ̀: ní ọjọ́ tí ó rà wọ́n padà lọ́wọ́ àwọn aninilára, ní ọjọ́ tí ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ hàn ní , àti iṣẹ́ àmì rẹ̀ ni ẹkùn Ṣoani Ó sọ omi wọn di ẹ̀jẹ̀; wọn kò lè mu láti odò wọn. Ó rán ọ̀wọ́ eṣinṣin láti pa wọ́n run, àti ọ̀pọ̀lọ́ tí ó bá wọn jẹun. Ó fi ọkà wọn fún láńtata, àwọn ìre oko wọn fún eṣú. Ó fi yìnyín ba àjàrà wọn jẹ́ ó bá èso sikamore wọn jẹ́. Ó fi ohun ọ̀sìn wọn fún yìnyín, agbo ẹran wọn fún mọ̀nàmọ́ná. Ó mú kíkorò ìbínú rẹ̀ wá sí wọn lára, ìrunú àti ìkáàánú, àti ìpọ́njú, nípa rírán angẹli apanirun sí wọn. Ó pèsè ipa fún ìbínú rẹ̀, òun kò gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú, ṣùgbọ́n ó fi ẹ̀mí wọ́n fún àjàkálẹ̀-ààrùn. Ó kọlu àwọn àkọ́bí ọmọ ọkùnrin , olórí agbára wọn nínú àgọ́ . Ṣùgbọ́n ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde bí ọ̀wọ́ ẹran; ó ṣọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí àgùntàn nínú aginjù. Ó dáàbò bò wọ́n dáradára, nítorí náà ni ẹ̀rù kò ṣe bà wọ́n ṣùgbọ́n òkun padé mọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Bákan náà ni ó mú wọn wá sí etí ilẹ̀ mímọ́ rẹ̀ òkè tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ti gbà Ó lé kèfèrí jáde níwájú wọn ó sì fi títa okùn pín ilẹ̀ náà fún wọn gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ ìní; ó mú àwọn ẹ̀yà ẹli jókòó ní ilẹ̀ wọn. Ṣùgbọ́n wọn dán Ọlọ́run wò wọn sì ṣọ̀tẹ̀ sí Ọ̀gá-ògo; wọn kò pa àṣẹ rẹ̀ mọ́. Ṣùgbọ́n wọ́n yípadà, wọn jẹ́ aláìṣòdodo gẹ́gẹ́ bí àwọn baba wọn wọ́n sì pẹ̀yìndà sí apákan bí ọrun ẹ̀tàn. Wọ́n bí i nínú pẹ̀lú ibi gíga wọn; wọn rú owú rẹ̀ sókè nípa òrìṣà wọn. Nígbà tí Ọlọ́run gbọ́ wọn, inú bí i gidigidi; ó kọ ẹli pátápátá. Ó kọ àgọ́ Ṣilo sílẹ̀, àgọ́ tí ó ti gbé kalẹ̀ láàrín àwọn ènìyàn. Ó rán àpótí ẹ̀rí, agbára rẹ̀ lọ sí ìgbèkùn, dídán ògo rẹ̀ lọ sí ọwọ́ àwọn ọ̀tá. Ó fi àwọn ènìyàn rẹ̀ lé idà lọ́wọ́, ó sì bínú sí àwọn ohun ìní rẹ̀. Iná run àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin wọn, àwọn ọmọbìnrin wọn kò sì ní orin ìgbéyàwó: àfi àlùfáà wọn fún idà, àwọn opó wọn kò sì le è sọkún. Olúwa sì jí gẹ́gẹ́ bí ẹni ojú oorun, gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin ti i jí kúrò nínú ìraníyè ọtí. Ó kọlu àwọn ọ̀tá rẹ̀ padà; ó fi wọn sínú ìtìjú ayérayé. Nígbà náà ni ó kọ́ àgọ́ ẹfu, kò sì yan ẹ̀yà , ṣùgbọ́n ó yan ẹ̀yà , òkè , èyí tí ó fẹ́ràn. Ó kọ́ ibi mímọ́ rẹ̀, ibi gíga, gẹ́gẹ́ bí ayé tí ó fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ títí láé. Ó yan ìránṣẹ́ rẹ̀ ó mú láti inú àwọn agbo ẹran; Ó mú un jáde nínú ìtọ́jú àgùntàn láti jẹ́ olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn rẹ̀ ọbu àti ẹli ogún un rẹ̀. Dafidi sì ṣọ́ wọn pẹ̀lú òtítọ́ inú ọkàn; pẹ̀lú ọwọ́ òye ni ó fi darí wọn.

Every verse in Psalms 78

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00