Psalms 8:7

“àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù, àti ẹranko igbó,”

Psalms 8:7 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible

Verse 7 of 9 in Psalms chapter 8 — Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible. Read it in context below, with maps, timelines and thematic connections beside the text.

Psalms 8 — full chapter (Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible)

Olúwa, Olúwa wa, orúkọ rẹ̀ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé! Ìwọ ti gbé ògo rẹ ga ju àwọn ọ̀run lọ. Láti ẹnu ọmọ ọwọ́ àti ọmọ ọmú ni o ti yan ìyìn nítorí àwọn ọ̀tá rẹ, láti pa àwọn ọ̀tá àti àwọn olùgbẹ̀san lẹ́nu mọ́. Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀, kí ni ènìyàn tí ìwọ ń rò nípa rẹ̀, àní ọmọ ènìyàn tí ìwọ ń ṣe ìtọ́jú rẹ̀? Ìwọ ṣe é ní írẹ̀lẹ̀ díẹ̀ ju Ọlọ́run lọ, ìwọ sì dé e ní adé ògo àti ọlá. Ìwọ mú un jẹ ọba lórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ rẹ; ìwọ sì fi ohun gbogbo sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀: àwọn agbo àgùntàn àti àwọn màlúù, àti ẹranko igbó, ẹyẹ ojú ọrun, àti ẹja inú Òkun, àti ohun tí ń wẹ nínú ipa Òkun. Olúwa, Olúwa wa, orúkọ rẹ ti ní ìyìn tó ní gbogbo ayé!

Every verse in Psalms 8

Chapter navigation

Biblica® ní oore ọ̀fẹ́ láti lo Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní™ / Biblica® Open Yoruba Contemporary Bible™ Copyright © 2009, 2017 by Biblica, Inc. “Biblica” is a trademark registered in the United States Patent and Trademark Office by Biblica, Inc. Used with permission. Licensed under CC BY-SA 4.0.

0:000:00